Joṣ 22 YCE

Joṣua Dá Àwọn Ẹ̀yà Ìhà Ìlà Oòrùn Pada Sílé

1 NIGBANA ni Joṣua pè awọn ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse,

2 O si wi fun wọn pe, Ẹnyin ti ṣe gbogbo eyiti Mose iranṣẹ OLUWA palaṣẹ fun nyin, ẹnyin si gbọ́ ohùn mi ni gbogbo eyiti mo palaṣẹ fun nyin:

3 Ẹnyin kò fi awọn arakunrin nyin silẹ lati ọjọ́ pipọ̀ wọnyi wá titi o fi di oni, ṣugbọn ẹnyin ṣe afiyesi ìlo ofin OLUWA Ọlọrun nyin.

4 Njẹ nisisiyi OLUWA Ọlọrun nyin ti fi isimi fun awọn arakunrin nyin, gẹgẹ bi o ti sọ fun wọn: njẹ nisisiyi ẹ pada, ki ẹ si lọ sinu agọ́ nyin, ati si ilẹ-iní nyin, ti Mose iranṣẹ OLUWA ti fun nyin ni ìha keji Jordani.

5 Kìki ki ẹ kiyesara gidigidi lati pa aṣẹ ati ofin mọ́, ti Mose iranṣẹ OLUWA fi fun nyin, lati fẹ́ OLUWA Ọlọrun nyin, ati lati ma rìn ni gbogbo ọ̀na rẹ̀, ati lati ma pa aṣẹ rẹ̀ mọ́, ati lati faramọ́ ọ, ati lati sìn i pẹlu àiya nyin gbogbo ati pẹlu ọkàn nyin gbogbo.

6 Bẹ̃ni Joṣua sure fun wọn, o si rán wọn lọ: nwọn si lọ sinu agọ́ wọn.

7 Njẹ fun àbọ ẹ̀ya Manasse ni Mose ti fi ilẹ-iní wọn fun ni Baṣani: ṣugbọn fun àbọ ẹ̀ya ti o kù ni Joṣua fi ilẹ-iní fun pẹlu awọn arakunrin wọn ni ìha ihin Jordani ni ìwọ-õrùn. Nigbati Joṣua si rán wọn pada lọ sinu agọ́ wọn, o sure fun wọn pẹlu,

8 O si wi fun wọn pe, Ẹ pada lọ pẹlu ọrọ̀ pipọ̀ si agọ́ nyin, ati pẹlu ohunọ̀sin pipọ̀, pẹlu fadakà, ati pẹlu wurà, ati pẹlu idẹ ati pẹlu irin, ati pẹlu aṣọ pipọ̀pipọ: ẹ bá awọn arakunrin nyin pín ikogun awọn ọtá nyin.

9 Awọn ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse si pada, nwọn si lọ kuro lọdọ awọn ọmọ Israeli lati Ṣilo, ti mbẹ ni ilẹ Kenaani, lati lọ si ilẹ Gileadi, si ilẹ iní wọn, eyiti nwọn ti gbà, gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA lati ọwọ́ Mose wá.

Pẹpẹ Tí Ó Wà Lẹ́bàá Odò Jọrdani

10 Nigbati nwọn si dé eti Jordani, ti mbẹ ni ilẹ Kenaani, awọn ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse mọ pẹpẹ kan lẹba Jordani, pẹpẹ ti o tobi lati wò.

11 Awọn ọmọ Israeli si gbọ́ pe, Kiyesi i, awọn ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse mọ pẹpẹ kan dojukọ ilẹ Kenaani, lẹba Jordani ni ìha keji awọn ọmọ Israeli.

12 Nigbati awọn ọmọ Israeli gbọ́ ọ, gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli kó ara wọn jọ ni Ṣilo, lati gòke lọ ibá wọn jagun.

13 Awọn ọmọ Israeli si rán Finehasi ọmọ Eleasari alufa si awọn ọmọ Reubeni, ati si awọn ọmọ Gadi, ati si àbọ ẹ̀ya Manasse ni ilẹ Gileadi;

14 Ati awọn olori mẹwa pẹlu rẹ̀, olori ile baba kọkan fun gbogbo ẹ̀ya Israeli; olukuluku si ni olori ile baba wọn ninu ẹgbẹgbẹrun Israeli.

15 Nwọn si dé ọdọ awọn ọmọ Reubeni, ati ọdọ awọn ọmọ Gadi, ati ọdọ àbọ ẹ̀ya Manasse, ni ilẹ Gileadi, nwọn si bá wọn sọ̀rọ pe,

16 Bayi ni gbogbo ijọ OLUWA wi, Ẹ̀ṣẹ kili eyiti ẹnyin da si Ọlọrun Israeli, lati pada li oni kuro lẹhin OLUWA, li eyiti ẹnyin mọ pẹpẹ kan fun ara nyin, ki ẹnyin ki o le ṣọ̀tẹ si OLUWA li oni?

17 Ẹ̀ṣẹ ti Peori kò to fun wa kọ́, ti a kò ti iwẹ̀mọ́ ninu rẹ̀ titi di oni, bi o tilẹ ṣe pe ajakalẹ-àrun wà ninu ijọ OLUWA,

18 Ti ẹnyin fi pada kuro lẹhin OLUWA li oni? Yio si ṣe, bi ẹnyin ti ṣọ̀tẹ si OLUWA li oni, li ọla, on o binu si gbogbo ijọ Israeli.

19 Njẹ bi o ba ṣepe ilẹ iní nyin kò ba mọ́, ẹ rekọja si ilẹ iní OLUWA, nibiti agọ́ OLUWA ngbé, ki ẹ si gbà ilẹ-iní lãrin wa: ṣugbọn ẹnyin má ṣe ṣọ̀tẹ si OLUWA, bẹ̃ni ki ẹ má ṣe ṣọ̀tẹ si wa, ni mimọ pẹpẹ miran fun ara nyin lẹhin pẹpẹ OLUWA Ọlọrun wa.

20 Ṣe bẹ̃ni Akani ọmọ Sera da ẹ̀ṣẹ niti ohun ìyasọtọ, ti ibinu si dé sori gbogbo ijọ Israeli? ọkunrin na kò nikan ṣegbé ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀.

21 Nigbana ni awọn ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse dahùn, nwọn si wi fun awọn olori ẹgbẹgbẹrun Israeli pe,

22 OLUWA, Ọlọrun awọn ọlọrun, OLUWA Ọlọrun awọn ọlọrun, On mọ̀, Israeli pẹlu yio si mọ̀; bi o ba ṣepe ni ìṣọtẹ ni, tabi bi ni irekọja si OLUWA, (má ṣe gbà wa li oni,)

23 Ni awa fi mọ pẹpẹ fun ara wa, lati yipada kuro lẹhin OLUWA; tabi bi o ba ṣe pe lati ru ẹbọ sisun, tabi ẹbọ ohunjijẹ, tabi ẹbọ alafia lori rẹ̀, ki OLUWA tikala rẹ̀ ki o bère rẹ̀.

24 Bi o ba ṣepe awa kò kuku ṣe e nitori aniyàn, ati nitori nkan yi pe, Lẹhinọla awọn ọmọ nyin le wi fun awọn ọmọ wa pe, Kili o kàn nyin niti OLUWA, Ọlọrun Israeli?

25 Nitoriti Ọlọrun ti fi Jordani pàla li agbedemeji awa ati ẹnyin, ẹnyin ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi; ẹnyin kò ní ipín niti OLUWA: bẹ̃li awọn ọmọ nyin yio mu ki awọn ọmọ wa ki o dẹkun ati ma bẹ̀ru OLUWA.

26 Nitorina li a ṣe wipe, Ẹ jẹ ki a mura nisisiyi lati mọ pẹpẹ kan, ki iṣe fun ẹbọ sisun, tabi fun ẹbọ kan:

27 Ṣugbọn ẹrí ni li agbedemeji awa ati ẹnyin, ati awọn iran wa lẹhin wa, ki awa ki o le ma fi ẹbọ sisun wa, ati ẹbọ wa, pẹlu ẹbọ alafia wa jọsìn fun OLUWA niwaju rẹ̀; ki awọn ọmọ nyin ki o má ba wi fun awọn ọmọ wa lẹhinọla pe, Ẹnyin kò ní ipín niti OLUWA.

28 Nitorina ni awa ṣe wipe, Yio si ṣe, nigbati nwọn ba wi bẹ̃ fun wa, tabi fun awọn iran wa lẹhinọla, awa o si wipe, Ẹ wò apẹrẹ pẹpẹ OLUWA, ti awọn baba wa mọ, ki iṣe fun ẹbọ sisun, bẹ̃ni ki iṣe fun ẹbọ; ṣugbọn o jasi ẹrí li agbedemeji awa ati ẹnyin.

29 Ki Ọlọrun má jẹ ki awa ki o ṣọ̀tẹ si OLUWA, ki awa si pada li oni kuro lẹhin OLUWA, lati mọ pẹpẹ fun ẹbọ sisun, fun ẹbọ ohunjije, tabi fun ẹbọ kan, lẹhin pẹpẹ OLUWA Ọlọrun wa ti mbẹ niwaju agọ́ rẹ̀.

30 Nigbati Finehasi alufa, ati awọn olori ijọ, ati awọn olori ẹgbẹgbẹrun Israeli ti o wà pẹlu rẹ̀, gbọ́ ọ̀rọ ti awọn ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati awọn ọmọ Manasse sọ, o dùnmọ́ wọn.

31 Finehasi ọmọ Eleasari alufa si wi fun awọn ọmọ Reubeni, ati fun awọn ọmọ Gadi, ati fun awọn ọmọ Manasse pe, Li oni li awa mọ̀ pe OLUWA wà lãrin wa, nitoriti ẹnyin kò dẹ̀ṣẹ yi si OLUWA: nisisiyi ẹnyin yọ awọn ọmọ Israeli kuro lọwọ OLUWA.

32 Finehasi ọmọ Eleasari alufa, ati awọn olori, si pada lati ọdọ awọn ọmọ Reubeni, ati lati ọdọ awọn ọmọ Gadi, ni ilẹ Gileadi, si ilẹ Kenaani, sọdọ awọn ọmọ Israeli, nwọn si mú ìhin pada tọ̀ wọn wá.

33 Ohun na si dùnmọ́ awọn ọmọ Israeli; awọn ọmọ Israeli si fi ibukún fun Ọlọrun, nwọn kò si sọ ti ati gòke tọ̀ wọn lọ ijà, lati run ilẹ na ninu eyiti awọn ọmọ Reubeni ati awọn ọmọ Gadi ngbé.

34 Awọn ọmọ Reubeni ati awọn ọmọ Gadi si sọ pẹpẹ na ni Edi: nwọn wipe, Nitori ẹrí ni li agbedemeji awa ati ẹnyin pe OLUWA on li Ọlọrun.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24