Joṣ 8 YCE

Gbígbà ati Pípa Ìlú Ai Run

1 OLUWA si wi fun Joṣua pe, Má ṣe bẹ̀ru, bẹ̃ni ki àiya ki o má ṣe fò ọ: mú gbogbo awọn ọmọ-ogun pẹlu rẹ ki iwọ ki o si dide, ki o si gòke lọ si Ai: kiyesi i, emi ti fi ọba Ai, ati awọn enia rẹ̀, ati ilunla rẹ̀, ati ilẹ rẹ̀ lé ọ lọwọ:

2 Iwọ o si ṣe si Ai ati si ọba rẹ̀ gẹgẹ bi iwọ ti ṣe si Jeriko ati si ọba rẹ̀: kìki ikogun rẹ̀, ati ohun-ọ̀sin rẹ̀, li ẹnyin o mú ni ikogun fun ara nyin: rán enia lọ iba lẹhin ilu na.

3 Joṣua si dide, ati gbogbo awọn ọmọ-ogun, lati gòke lọ si Ai: Joṣua si yàn ẹgba mẹdogun, alagbara akọni, o si rán wọn lo li oru.

4 O si paṣẹ fun wọn pe, Wò o, ẹnyin o ba tì ilu na, ani lẹhin ilu na: ẹ má ṣe jìna pupọ̀ si ilu na, ṣugbọn ki gbogbo nyin ki o murasilẹ.

5 Ati emi, ati gbogbo awọn enia ti o wà pẹlu mi, yio sunmọ ilu na: yio si ṣe, nigbati nwọn ba jade si wa, gẹgẹ bi ti ìgba iṣaju, awa o si sá niwaju wọn;

6 Nitoriti nwọn o jade si wa, titi awa o fi fà wọn jade kuro ni ilu; nitoriti nwọn o wipe, Nwọn sá niwaju wa, gẹgẹ bi ti ìgba iṣaju; nitorina li awa o sá niwaju wọn:

7 Nigbana li ẹnyin o dide ni buba, ẹnyin o si gbà ilu na: nitoriti OLUWA Ọlọrun nyin yio fi i lé nyin lọwọ.

8 Yio si ṣe, nigbati ẹnyin ba gbà ilu na tán, ki ẹnyin ki o si tinabọ ilu na; gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA ni ki ẹnyin ki o ṣe: wò o, mo ti fi aṣẹ fun nyin na.

9 Nitorina ni Joṣua ṣe rán wọn lọ: nwọn lọ iba, nwọn si joko li agbedemeji Beti-eli ati Ai, ni ìha ìwọ-õrùn Ai: ṣugbọn Joṣua dó li oru na lãrin awọn enia.

10 Joṣua si dide ni kùtukutu owurọ̀, o si kà awọn enia, o si gòke lọ si Ai, on, ati awọn àgba Israeli niwaju awọn enia.

11 Ati gbogbo awọn enia, ani awọn ọmọ-ogun ti mbẹ pẹlu rẹ̀, nwọn gòke lọ, nwọn si sunmọtosi, nwọn si wá siwaju ilu na, nwọn si dó ni ìha ariwa Ai; afonifoji si mbẹ li agbedemeji wọn ati Ai.

12 O si mú to bi ẹgbẹdọgbọ̀n enia, o si fi wọn si ibuba li agbedemeji Betieli ati Ai, ni ìha ìwọ-õrùn ilu na.

13 Nwọn si yàn awọn enia si ipò, ani gbogbo ogun ti mbẹ ni ìha ariwa ilu na, ati awọn enia ti o ba ni ìha ìwọ-õrùn ilu na; Joṣua si lọ li oru na sãrin afonifoji na.

14 O si ṣe, nigbati ọba Ai ri i, nwọn yára nwọn si dide ni kùtukutu, awọn ọkunrin ilu na si jade si Israeli lati jagun, ati on ati gbogbo awọn enia rẹ̀, niwaju pẹtẹlẹ̀, ibi ti a ti yàn tẹlẹ; ṣugbọn on kò mọ̀ pe awọn ti o ba dè e mbẹ lẹhin ilu.

15 Joṣua ati gbogbo awọn Israeli si ṣe bi ẹniti a lé niwaju wọn, nwọn si sá gbà ọ̀na aginjú.

16 A si pe gbogbo enia ti mbẹ ni Ai jọ lati lepa wọn: nwọn si lepa Joṣua, a si fà wọn jade kuro ni ilu.

17 Kò si kù ọkunrin kan ni Ai tabi Beti-eli, ti kò jade tọ̀ Israeli: nwọn si fi ilú nla silẹ ni ṣíṣí nwọn si lepa Israeli.

18 OLUWA si wi fun Joṣua pe, Nà ọ̀kọ ti mbẹ li ọwọ́ rẹ nì si Ai; nitoriti emi o fi i lé ọ lọwọ. Joṣua si nà ọ̀kọ na ti o ni li ọwọ́ rẹ̀ si ilu na.

19 Awọn ti o ba si dide kánkan kuro ni ipò wọn, bi o si ti nàwọ́ rẹ̀, nwọn sare, nwọn si wọ̀ ilu na lọ, nwọn si gbà a; nwọn si yára tinabọ ilu na.

20 Nigbati awọn ọkunrin Ai boju wo ẹhin wọn, kiyesi i, nwọn ri ẹ̃fi ilu na ngòke lọ si ọrun, nwọn kò si lí agbara lati gbà ihin tabi ọhún sálọ: awọn enia ti o sá lọ si aginjù si yipada si awọn ti nlepa.

21 Nigbati Joṣua ati gbogbo Israeli ri bi awọn ti o ba ti gbà ilu, ti ẹ̃fi ilu na si gòke, nwọn si yipada, nwọn si pa awọn ọkunrin Ai.

22 Awọn ti ara keji si yọ si wọn lati ilu na wá; bẹ̃ni nwọn wà li agbedemeji Israeli, awọn miran li apa ihin, awọn miran li apa ọhún: nwọn si pa wọn, bẹ̃ni nwọn kò si jẹ ki ọkan ki o kù tabi ki o sálọ ninu wọn.

23 Nwọn si mú ọba Ai lãye, nwọn si mú u wá sọdọ Joṣua.

24 O si ṣe, nigbati Israeli pari pipa gbogbo awọn ara ilu Ai ni igbẹ́, ati ni aginjù ni ibi ti nwọn lé wọn si, ti gbogbo wọn si ti oju idà ṣubu, titi a fi run wọn, ni gbogbo awọn ọmọ Israeli pada si Ai, nwọn si fi oju idà kọlù u.

25 O si ṣe, gbogbo awọn ti o ṣubu ni ijọ́ na, ati ọkunrin ati obinrin, jẹ́ ẹgba mẹfa, ani gbogbo ọkunrin Ai.

26 Nitoriti Joṣua kò fà ọwọ́ rẹ̀ ti o fi nà ọ̀kọ sẹhin, titi o fi run gbogbo awọn ara ilu Ai tútu.

27 Kìki ohun-ọ̀sin ati ikogun ilu na ni Israeli kó fun ara wọn, gẹgẹ bi ọ̀rọ OLUWA ti o palaṣẹ fun Joṣua.

28 Joṣua si kun Ai, o sọ ọ di òkiti lailai, ani ahoro titi di oni-oloni.

29 Ọba Ai li o si so rọ̀ lori igi titi di aṣalẹ: bi õrùn si ti wọ̀, Joṣua paṣẹ ki a sọ okú rẹ̀ kuro lori igi kalẹ, ki a si wọ́ ọ jù si atiwọ̀ ibode ilu na, ki a si kó òkiti nla okuta lé e lori, ti mbẹ nibẹ̀ titi di oni-oloni.

Joṣua Ka Òfin ní Òkè Ebali

30 Nigbana ni Joṣua tẹ́ pẹpẹ kan fun OLUWA, Ọlọrun Israeli, li òke Ebali,

31 Gẹgẹ bi Mose iranṣẹ OLUWA ti paṣẹ fun awọn ọmọ Israeli, gẹgẹ bi a ti kọ ọ ninu iwé ofin Mose, pẹpẹ odidi okuta, lara eyiti ẹnikan kò fi irin kan: nwọn si ru ẹbọ sisun lori rẹ̀ si OLUWA, nwọn si ru ẹbọ alafia.

32 O si kọ apẹrẹ ofin Mose sara okuta na, ti o kọ niwaju awọn ọmọ Israeli.

33 Ati gbogbo Israeli, ati awọn àgba wọn, ati awọn olori, ati awọn onidajọ wọn, duro li apa ihin ati li apa ọhún apoti ẹrí niwaju awọn alufa awọn ọmọ Lefi, ti o rù apoti majẹmu OLUWA, ati alejò ati ibilẹ; àbọ wọn kọjusi òke Gerisimu; ati àbọ wọn kọjusi òke Ebali, gẹgẹ bi Mose iranṣẹ OLUWA ti paṣẹ rí, pe ki nwọn ki o sure fun awọn enia Israeli.

34 Lẹhin eyi o si kà gbogbo ọ̀rọ ofin, ibukún ati egún, gẹgẹ bi gbogbo eyiti a kọ ninu iwé ofin.

35 Kò kù ọ̀rọ kan ninu gbogbo eyiti Mose palaṣẹ, ti Joṣua kò kà niwaju gbogbo ijọ Israeli, ati awọn obinrin, ati awọn ọmọ wẹrẹ, ati awọn alejò ti nrìn lãrin wọn.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24