1 O si ṣe, nigbati gbogbo awọn ọba Amori, ti o wà ni ìha keji Jordani ni ìwọ-õrùn, ati gbogbo awọn ọba Kenaani ti mbẹ leti okun, gbọ́ pe OLUWA ti mu omi Jordani gbẹ kuro niwaju awọn ọmọ Israeli, titi awa fi là a kọja, ni àiya wọn já, bẹ̃li ẹmi kò sí ninu wọn mọ́, nitori awọn ọmọ Israeli.
2 Nigbana li OLUWA wi fun Joṣua pe, Fi okuta ṣe abẹ ki iwọ ki o si tun kọ awọn ọmọ Israeli nilà lẹ̃keji.
3 Joṣua si ṣe abẹ okuta, o si kọ awọn ọmọ Israeli nilà, ni Gibeati-haaralotu.
4 Idí rẹ̀ li eyi ti Joṣua fi kọ wọn nilà: gbogbo awọn enia ti o ti Egipti jade wá, ti o ṣe ọkunrin, ani gbogbo awọn ọmọ-ogun, nwọn kú li aginjù, li ọ̀na, lẹhin igbati nwọn jade kuro ni Egipti.
5 Nitori gbogbo awọn enia ti o jade ti ibẹ̀ wà, a kọ wọn nilà: ṣugbọn gbogbo awọn enia ti a bi li aginjù li ọ̀na, bi nwọn ti jade kuro ni Egipti, awọn ni a kò kọnilà.
6 Nitoriti awọn ọmọ Israeli rìn li ogoji ọdún li aginjù, titi gbogbo iran na, ani awọn ologun, ti o jade ti Egipti wá fi run, nitoriti nwọn kò gbà ohùn OLUWA gbọ́: awọn ti OLUWA bura fun pe, on ki yio jẹ ki wọn ri ilẹ na, ti OLUWA bura fun awọn baba wọn lati fi fun wa, ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin.
7 Ati awọn ọmọ wọn, ti o gbé dide ni ipò wọn, awọn ni Joṣua kọnilà: nitoriti nwọn wà li alaikọlà, nitoriti a kò kọ wọn nilà li ọ̀na.
8 O si ṣe, nigbati nwọn kọ gbogbo awọn enia na nilà tán, nwọn joko ni ipò wọn ni ibudó, titi ara wọn fi dá.
9 OLUWA si wi fun Joṣua pe, Li oni ni mo yi ẹ̀gan Egipti kuro lori nyin. Nitorina li a ṣe npè orukọ ibẹ̀ ni Gilgali titi o fi di oni yi.
10 Awọn ọmọ Israeli si dó ni Gilgali; nwọn si ṣe ajọ irekọja li ọjọ́ kẹrinla oṣù li ọjọ́ alẹ, ni pẹtẹlẹ̀ Jeriko.
11 Nwọn si jẹ ọkà gbigbẹ ilẹ na ni ijọ́ keji lẹhin irekọja, àkara alaiwu, ọkà didin li ọjọ̀ na gan.
12 Manna si dá ni ijọ́ keji lẹhin igbati nwọn ti jẹ okà gbigbẹ ilẹ na; awọn ọmọ Israeli kò si ri manna mọ́; ṣugbọn nwọn jẹ eso ilẹ Kenaani li ọdún na.
13 O si ṣe, nigbati Joṣua wà leti Jeriko, o gbé oju rẹ̀ soke o si wò, si kiyesi i, ọkunrin kan duro niwaju rẹ̀ pẹlu idà fifayọ li ọwọ́ rẹ̀: Joṣua si tọ̀ ọ lọ, o si wi fun u pe, Ti wa ni iwọ nṣe, tabi ti ọtá wa?
14 O si wipe, Bẹ̃kọ; ṣugbọn bi olori ogun OLUWA ni mo wá si nisisiyi. Joṣua si wolẹ niwaju rẹ̀, o si foribalẹ, o si wi fun pe, Kili oluwa mi ni isọ fun iranṣẹ rẹ̀?
15 Olori-ogun OLUWA si wi fun Joṣua pe, Bọ́ salubata rẹ kuro li ẹsẹ̀ rẹ; nitoripe ibi ti iwọ gbé duro nì ibi mimọ́ ni. Joṣua si ṣe bẹ̃.