Joṣ 11 YCE

Joṣua Ṣẹgun Jabini ati Àwọn tí Wọ́n Darapọ̀ Mọ́ ọn

1 O si ṣe, nigbati Jabini ọba Hasoru gbọ́ nkan wọnyi, o ranṣẹ si Jobabu ọba Madoni, ati si ọba Ṣimroni, ati si ọba Akṣafu,

2 Ati si awọn ọba ti mbẹ ni ìha ariwa, lori òke, ati ti pẹtẹlẹ̀ ni ìha gusù ti Kinnerotu, ati ni ilẹ titẹju, ati ni ilẹ òke Doru ni ìha ìwọ-õrùn,

3 Ati si awọn ara Kenaani ni ìha ìla-õrùn ati ni ìha ìwọ-õrùn, ati awọn Amori, ati si awọn Hitti, ati si awọn Perissi, ati si awọn Jebusi lori òke, ati si awọn Hifi nisalẹ Hermoni ni ilẹ Mispa.

4 Nwọn si jade, awọn ati gbogbo ogun wọn pẹlu wọn, ọ̀pọlọpọ enia, bi yanrin ti mbẹ li eti okun fun ọ̀pọ, ati ẹṣin ati kẹkẹ́ pipọ̀pipọ.

5 Gbogbo awọn ọba wọnyi si pejọ pọ̀, nwọn wá nwọn si dó ṣọkan ni ibi omi Meromu, lati fi ijà fun Israeli.

6 OLUWA si wi fun Joṣua pe, Má ṣe bẹ̀ru nitori wọn: nitori li ọla li akokò yi emi o fi gbogbo wọn tọrẹ niwaju Israeli ni pipa: iwọ o já patì ẹṣin wọn, iwọ o si fi iná sun kẹkẹ́ wọn.

7 Bẹ̃ni Joṣua, ati gbogbo awọn ọmọ-ogun pẹlu rẹ̀, yọ si wọn lojijì ni ibi omi Meromu, nwọn si kọlù wọn.

8 OLUWA si fi wọn lé Israeli lọwọ, nwọn si kọlù wọn, nwọn si lé wọn titi dé Sidoni nla ati titi dé Misrefoti-maimu, ati dé afonifoji Mispa ni ìha ìla-õrùn; nwọn si pa wọn tobẹ̃ ti kò kù ẹnikan silẹ fun wọn.

9 Joṣua si ṣe si wọn gẹgẹ bi OLUWA ti paṣẹ fun u: o já patì ẹṣin wọn, o si fi iná sun kẹkẹ́ wọn.

10 Joṣua si pada li akokò na, o si kó Hasoru, o si fi idà pa ọba rẹ̀: nitori li atijọ́ rí Hasoru li olori gbogbo ilẹ-ọba wọnni.

11 Nwọn si fi oju idà pa gbogbo ọkàn ti mbẹ ninu rẹ̀, nwọn run wọn patapata: a kò kù ẹnikan ti nmí silẹ: o si fi iná kun Hasoru.

12 Ati gbogbo ilu awọn ọba wọnni, ati gbogbo ọba wọn, ni Joṣua kó, o si fi oju idà kọlù wọn, o si pa wọn run patapata, gẹgẹ bi Mose iranṣẹ OLUWA ti palaṣẹ.

13 Ṣugbọn awọn ilu ti o duro lori òke wọn, Israeli kò sun ọkan ninu wọn, bikoṣe Hasoru nikan; eyi ni Joṣua fi iná sun.

14 Ati gbogbo ikogun ilu wonyi, ati ohunọ̀sin, ni awọn ọmọ Israeli kó fun ara wọn; ṣugbọn gbogbo awọn ọkunrin ni nwọn fi oju kọlù, titi nwọn fi pa wọn run, nwọn kò kù ẹnikan silẹ ti nmí.

15 Gẹgẹ bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose iranṣẹ rẹ̀, bẹ̃ni Mose paṣẹ fun Joṣua: bẹ̃ni Joṣua si ṣe; on kò kù ohun kan silẹ ninu gbogbo ohun ti OLUWA palaṣẹ fun Mose.

Àwọn Ilẹ̀ Tí Joṣua Gbà

16 Bẹ̃ni Joṣua gbà gbogbo ilẹ na, ilẹ òke, ati gbogbo ilẹ Gusù, ati gbogbo ilẹ Goṣeni, ati ilẹ titẹju, ati pẹtẹlẹ̀, ati ilẹ òke Israeli, ati ilẹ titẹju rẹ̀;

17 Lati òke Halaki lọ, ti o lọ soke Seiri, ani dé Baali-gadi ni afonifoji Lebanoni nisalẹ òke Hermoni: ati gbogbo awọn ọba wọn li o kó, o si kọlù wọn, o si pa wọn.

18 Joṣua si bá gbogbo awọn ọba wọnni jagun li ọjọ́ pipọ̀.

19 Kò sí ilu kan ti o bá awọn ọmọ Israeli ṣọrẹ, bikoṣe awọn Hifi awọn ara ilu Gibeoni: gbogbo wọn ni nwọn fi ogun gbà.

20 Nitori lati ọdọ OLUWA li a ti mu ọkàn wọn le, ki nwọn ki o le jade ogun tọ̀ Israeli wá, ki o le pa wọn run patapata, ki nwọn ki o má si ṣe ri ojurere, ṣugbọn ki o le pa wọn run, gẹgẹ bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.

21 Li akokò na ni Joṣua wá, ti o si ke awọn ọmọ Anaki kuro ni ilẹ òke, kuro ni Hebroni, kuro ni Debiri, kuro ni Anabu, ati kuro ni gbogbo ilẹ òke Juda, ati kuro ni gbogbo ilẹ òke Israeli: Joṣua run wọn patapata pẹlu ilu wọn.

22 Kò kù ẹnikan ninu awọn ọmọ Anaki ni ilẹ awọn ọmọ Israeli: bikoṣe ni Gasa, ni Gati, ati ni Aṣdodu, ni nwọn kù si.

23 Bẹ̃ni Joṣua gbà gbogbo ilẹ na, gẹgẹ bi ohun gbogbo ti OLUWA ti wi fun Mose; Joṣua si fi i fun Israeli ni ilẹ-iní, gẹgẹ bi ipín wọn nipa ẹ̀ya wọn. Ilẹ na si simi lọwọ ogun.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24