Joṣ 23 YCE

Ọ̀rọ̀ ìdágbére Tí Joṣua Sọ

1 O si ṣe li ọjọ́ pipọ̀ lẹhin ti OLUWA ti fi isimi fun Israeli lọwọ gbogbo awọn ọtá wọn yiká, ti Joṣua di arugbó, ti o si pọ̀ li ọjọ́;

2 Joṣua si pè gbogbo Israeli, ati awọn àgba wọn, ati awọn olori wọn, ati awọn onidajọ wọn, ati awọn ijoye wọn, o si wi fun wọn pe, Emi di arugbó tán, emi si pọ̀ li ọjọ́:

3 Ẹnyin si ti ri ohun gbogbo ti OLUWA Ọlọrun nyin ti ṣe si gbogbo orilẹ-ède wọnyi nitori nyin; nitori OLUWA Ọlọrun nyin, on li ẹniti o ti jà fun nyin.

4 Wò o, emi ti pín awọn orilẹ-ède wọnyi ti o kù fun nyin, ni ilẹ-iní fun awọn ẹ̀ya nyin, lati Jordani lọ, pẹlu gbogbo awọn orilẹ-ède ti mo ti ke kuro, ani titi dé okun nla ni ìha ìwọ-õrùn.

5 OLUWA Ọlọrun nyin, on ni yio tì wọn jade kuro niwaju nyin, yio si lé wọn kuro li oju nyin; ẹnyin o si ní ilẹ wọn, gẹgẹ bi OLUWA Ọlọrun nyin ti sọ fun nyin.

6 Nitorina ẹ mura gidigidi lati tọju ati lati ṣe ohun gbogbo ti a kọ sinu iwé ofin Mose, ki ẹnyin ki o má ṣe yipada kuro ninu rẹ̀ si ọwọ́ ọtún tabi si ọwọ́ òsi;

7 Ki ẹnyin ki o má ṣe wá sãrin awọn orilẹ-ède wọnyi, awọn wọnyi ti o kù pẹlu nyin; ki ẹnyin má ṣe da orukọ oriṣa wọn, bẹ̃ni ki ẹ má ṣe fi wọn bura, ẹ má ṣe sìn wọn, bẹ̃ni ki ẹ má ṣe tẹriba fun wọn:

8 Ṣugbọn ki ẹnyin faramọ́ OLUWA Ọlọrun nyin, gẹgẹ bi ẹnyin ti nṣe titi di oni.

9 Nitoriti OLUWA ti lé awọn orilẹ-ède nla ati alagbara kuro niwaju nyin; ṣugbọn bi o ṣe ti nyin ni, kò sí ọkunrin kan ti o ti iduro niwaju nyin titi di oni.

10 ọkunrin kan ninu nyin yio lé ẹgbẹrun: nitoripe OLUWA Ọlọrun nyin, on li ẹniti njà fun nyin, gẹgẹ bi o ti sọ fun nyin.

11 Nitorina ẹ kiyesara nyin gidigidi, ki ẹ fẹ́ OLUWA Ọlọrun nyin.

12 Ṣugbọn bi ẹ ba daṣà ati pada, ti ẹ si faramọ́ iyokù awọn orile-ède wọnyi, ani awọn wọnyi ti o kù lãrin nyin, ti ẹ si bá wọn gbeyawo, ti ẹ si nwọle tọ̀ wọn, ti awọn si nwọle tọ̀ nyin:

13 Ki ẹnyin ki o mọ̀ dajudaju pe OLUWA Ọlọrun nyin ki yio lé awọn orilẹ-ède wọnyi jade mọ́ kuro niwaju nyin; ṣugbọn nwọn o jẹ́ okùn-didẹ ati ẹgẹ́ fun nyin, ati paṣán ni ìha nyin, ati ẹgún li oju nyin, titi ẹ o fi ṣegbé kuro ni ilẹ daradara yi ti OLUWA Ọlọrun nyin ti fi fun nyin.

14 Ẹnyin kiyesi i, li oni emi nlọ si ọ̀na gbogbo aiye: ényin si mọ̀ li àiya nyin gbogbo, ati li ọkàn nyin gbogbo pe, kò sí ohun kan ti o tase ninu ohun rere gbogbo ti OLUWA Ọlọrun nyin ti sọ niti nyin; gbogbo rẹ̀ li o ṣẹ fun nyin, kò si sí ohun ti o tase ninu rẹ̀.

15 Yio si ṣe, gẹgẹ bi ohun rere gbogbo ti ṣẹ fun nyin, ti OLUWA Ọlọrun nyin ti sọ fun nyin; bẹ̃ni OLUWA yio mú ibi gbogbo bá nyin, titi yio fi pa nyin run kuro ni ilẹ daradara yi ti OLUWA Ọlọrun nyin ti fi fun nyin.

16 Nigbati ẹnyin ba re majẹmu OLUWA Ọlọrun nyin kọja, ti o palaṣẹ fun nyin, ti ẹ ba si lọ, ti ẹ ba nsìn oriṣa ti ẹnyin ba tẹ̀ ori nyin bà fun wọn; nigbana ni ibinu OLUWA yio rú si nyin, ẹnyin o si ṣegbé kánkan kuro ni ilẹ daradara ti o ti fi fun nyin.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24