Joṣ 3 YCE

Àwọn Ọmọ Israẹli La Odò Jọdani Kọjá

1 JOṢUA si dide ni kùtukutu owurọ̀, nwọn si ṣí kuro ni Ṣittimu, nwọn si dé Jordani, on ati gbogbo awọn ọmọ Israeli; nwọn si sùn sibẹ̀ ki nwọn ki o to gòke odò.

2 O si ṣe lẹhin ijọ́ mẹta, ni awọn olori là ãrin ibudó já;

3 Nwọn si paṣẹ fun awọn enia, wipe, Nigbati ẹnyin ba ri apoti majẹmu OLUWA Ọlọrun nyin, ti ẹ ba si ri awọn alufa awọn ọmọ Lefi rù u, nigbana li ẹnyin o ṣí kuro ni ipò nyin, ẹnyin o si ma tọ̀ ọ lẹhin.

4 Ṣugbọn alafo yio wà li agbedemeji ti ẹnyin tirẹ̀, to bi ìwọn ẹgba igbọnwọ: ẹ má ṣe sunmọ ọ, ki ẹnyin ki o le mọ̀ ọ̀na ti ẹnyin o gbà; nitoriti ẹnyin kò gbà ọ̀na yi rí.

5 Joṣua si wi fun awọn enia pe, Ẹ yà ara nyin simimọ́: nitori li ọla OLUWA yio ṣe ohuniyanu lãrin nyin.

6 Joṣua si wi fun awọn alufa pe, Ẹ gbé apoti majẹmu na, ki ẹ si kọja siwaju awọn enia. Nwọn si gbé apoti majẹmu na, nwọn si ṣaju awọn enia.

7 OLUWA si wi fun Joṣua pe, Li oni yi li emi o bẹ̀rẹsi gbé ọ ga li oju gbogbo Israeli, ki nwọn ki o le mọ̀ pe, gẹgẹ bi mo ti wà pẹlu Mose, bẹ̃li emi o wà pẹlu rẹ.

8 Iwọ o si paṣẹ fun awọn alufa ti o rù apoti majẹmu na pe, Nigbati ẹnyin ba dé eti odò Jordani, ki ẹnyin ki o duro jẹ ni Jordani.

9 Joṣua si wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹ sunmọ ihin, ki ẹ si gbọ́ ọ̀rọ OLUWA Ọlọrun nyin.

10 Joṣua si wipe, Nipa eyi li ẹnyin o mọ̀ pe Ọlọrun alãye mbẹ lãrin nyin, ati pe dajudaju on o lé awọn ara Kenaani, ati awọn Hitti, ati awọn Hifi, ati awọn Perissi, ati awọn Girgaṣi ati awọn Amori, ati awọn Jebusi, kuro niwaju nyin.

11 Kiyesi i, apoti majẹmu OLUWA gbogbo aiye ngòke lọ ṣaju nyin lọ si Jordani.

12 Njẹ nitorina, ẹ mu ọkunrin mejila ninu awọn ẹ̀ya Israeli, ọkunrin kan ninu olukuluku ẹ̀ya.

13 Yio si ṣe, lojukanna bi atẹlẹsẹ̀ awọn alufa ti o rù apoti OLUWA, Oluwa gbogbo aiye, ba ti tẹ̀ omi Jordani, omi Jordani yio ke kuro, ani omi ti nti òke ṣànwá; yio si duro bi òkiti kan.

14 O si ṣe, nigbati awọn enia ṣí kuro ninu agọ́ wọn, lati gòke Jordani, ti awọn alufa si rù apoti majẹmu wà niwaju awọn enia;

15 Bi awọn ti o rù apoti si ti dé Jordani, ti awọn alufa ti o rù apoti na si tẹ̀ ẹsẹ̀ wọn bọ̀ eti omi na, (nitoripe odò Jordani a ma kún bò gbogbo bèbe rẹ̀ ni gbogbo akokò ikore,)

16 Ni omi ti nti oke ṣàn wá duro, o si ga jìna rére bi òkiti li ọnà ni ilu Adamu, ti o wà lẹba Saretani: eyiti o si ṣàn sodò si ìha okun pẹtẹlẹ̀, ani Okun Iyọ̀, a ke wọn kuro patapata: awọn enia si gòke tàra si Jeriko.

17 Awọn alufa ti o rù apoti majẹmu OLUWA, si duro ṣinṣin lori ilẹ gbigbẹ lãrin Jordani, ati gbogbo awọn enia Israeli kọja lori ilẹ gbigbẹ, titi gbogbo awọn enia na fi gòke Jordani tán.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24