3 Nitori Mose ti fi ilẹ-iní fun awọn ẹ̀ya meji ati àbọ ẹ̀ya li apa keji Jordani: ṣugbọn awọn ọmọ Lefi ni on kò fi ilẹ-iní fun lãrin wọn.
4 Nitoripe ẹ̀ya meji ni ẹ̀ya awọn ọmọ Josefu, Manasse ati Efraimu: nitorina nwọn kò si fi ipín fun awọn ọmọ Lefi ni ilẹ na, bikoṣe ilu lati ma gbé, pẹlu àgbegbe ilu wọn fun ohunọ̀sin wọn ati ohun-iní wọn.
5 Gẹgẹ bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose, bẹ̃ni awọn ọmọ Israeli ṣe, nwọn si pín ilẹ na.
6 Nigbana ni awọn ọmọ Juda wá sọdọ Joṣua ni Gilgali: Kalebu ọmọ Jefunne ti Kenissi si wi fun u pe, Iwọ mọ̀ ohun ti OLUWA wi fun Mose enia Ọlọrun nipa temi tirẹ ni Kadeṣi-barnea.
7 Ẹni ogoji ọdún ni mi nigbati Mose iranṣẹ OLUWA rán mi lati Kadeṣi-barnea lọ ṣamí ilẹ na; mo si mú ìhin fun u wá gẹgẹ bi o ti wà li ọkàn mi.
8 Ṣugbọn awọn arakunrin mi ti o gòke lọ já awọn enia li àiya: ṣugbọn emi tọ̀ OLUWA Ọlọrun mi lẹhin patapata.
9 Mose si bura li ọjọ́ na wipe, Nitõtọ ilẹ ti ẹsẹ̀ rẹ ti tẹ̀ nì, ilẹ-iní rẹ ni yio jẹ́, ati ti awọn ọmọ rẹ lailai, nitoriti iwọ tọ̀ OLUWA Ọlọrun mi lẹhin patapata.