7 Aini, Rimmoni, ati Eteri, ati Aṣani; ilu mẹrin pẹlu ileto wọn:
8 Ati gbogbo ileto ti o yi ilu wọnyi ká dé Baalati-beeri, Rama ti Gusù. Eyi ni ilẹ-iní ẹ̀ya awọn ọmọ Simeoni gẹgẹ bi idile wọn.
9 Ninu ipín awọn ọmọ Juda ni awọn ọmọ Simeoni ni ilẹ-iní: nitori ipín awọn ọmọ Juda pọ̀ju fun wọn: nitorina ni awọn ọmọ Simeoni fi ní ilẹ-iní lãrin ilẹ-iní wọn.
10 Ilẹ kẹta yọ fun awọn ọmọ Sebuluni gẹgẹ bi idile wọn: àla ilẹ-iní wọn si dé Saridi:
11 Àla wọn gòke lọ si ìha ìwọ-õrùn, ani titi o fi dé Marala, o si dé Dabaṣeti; o si dé odò ti mbẹ niwaju Jokneamu;
12 O si ṣẹri lati Saridi lọ ni ìha ìla-õrùn si ìla-õrùn dé àla Kisloti-tabori; o si yọ si Daberati; o si jade lọ si Jafia;
13 Ati lati ibẹ̀ o kọja ni ìha ìla-õrùn si Gati-heferi, dé Ẹti-kasini; o si yọ si Rimmoni titi o fi dé Nea;