21 O si wipe, Gẹgẹ bi ọ̀rọ nyin, bẹ̃ni ki o ri. O si rán wọn lọ, nwọn si lọ: o si so okùn ododó na si oju-ferese.
22 Nwọn si lọ, nwọn si dé ori òke, nwọn si gbé ibẹ̀ ni ijọ́ mẹta, titi awọn alepa fi pada: awọn alepa wá wọn ni gbogbo ọ̀na, ṣugbọn nwọn kò ri wọn.
23 Bẹ̃li awọn ọkunrin meji na pada, nwọn si sọkalẹ lori òke, nwọn si kọja, nwọn si tọ̀ Joṣua ọmọ Nuni wá; nwọn si sọ ohun gbogbo ti o bá wọn fun u.
24 Nwọn si wi fun Joṣua pe, Nitõtọ li OLUWA ti fi gbogbo ilẹ na lé wa lọwọ; nitoripe ọkàn gbogbo awọn ara ilẹ yi di omi nitori wa.