13 Awọn ọmọ Israeli si rán Finehasi ọmọ Eleasari alufa si awọn ọmọ Reubeni, ati si awọn ọmọ Gadi, ati si àbọ ẹ̀ya Manasse ni ilẹ Gileadi;
14 Ati awọn olori mẹwa pẹlu rẹ̀, olori ile baba kọkan fun gbogbo ẹ̀ya Israeli; olukuluku si ni olori ile baba wọn ninu ẹgbẹgbẹrun Israeli.
15 Nwọn si dé ọdọ awọn ọmọ Reubeni, ati ọdọ awọn ọmọ Gadi, ati ọdọ àbọ ẹ̀ya Manasse, ni ilẹ Gileadi, nwọn si bá wọn sọ̀rọ pe,
16 Bayi ni gbogbo ijọ OLUWA wi, Ẹ̀ṣẹ kili eyiti ẹnyin da si Ọlọrun Israeli, lati pada li oni kuro lẹhin OLUWA, li eyiti ẹnyin mọ pẹpẹ kan fun ara nyin, ki ẹnyin ki o le ṣọ̀tẹ si OLUWA li oni?
17 Ẹ̀ṣẹ ti Peori kò to fun wa kọ́, ti a kò ti iwẹ̀mọ́ ninu rẹ̀ titi di oni, bi o tilẹ ṣe pe ajakalẹ-àrun wà ninu ijọ OLUWA,
18 Ti ẹnyin fi pada kuro lẹhin OLUWA li oni? Yio si ṣe, bi ẹnyin ti ṣọ̀tẹ si OLUWA li oni, li ọla, on o binu si gbogbo ijọ Israeli.
19 Njẹ bi o ba ṣepe ilẹ iní nyin kò ba mọ́, ẹ rekọja si ilẹ iní OLUWA, nibiti agọ́ OLUWA ngbé, ki ẹ si gbà ilẹ-iní lãrin wa: ṣugbọn ẹnyin má ṣe ṣọ̀tẹ si OLUWA, bẹ̃ni ki ẹ má ṣe ṣọ̀tẹ si wa, ni mimọ pẹpẹ miran fun ara nyin lẹhin pẹpẹ OLUWA Ọlọrun wa.