3 Ẹnyin si ti ri ohun gbogbo ti OLUWA Ọlọrun nyin ti ṣe si gbogbo orilẹ-ède wọnyi nitori nyin; nitori OLUWA Ọlọrun nyin, on li ẹniti o ti jà fun nyin.
4 Wò o, emi ti pín awọn orilẹ-ède wọnyi ti o kù fun nyin, ni ilẹ-iní fun awọn ẹ̀ya nyin, lati Jordani lọ, pẹlu gbogbo awọn orilẹ-ède ti mo ti ke kuro, ani titi dé okun nla ni ìha ìwọ-õrùn.
5 OLUWA Ọlọrun nyin, on ni yio tì wọn jade kuro niwaju nyin, yio si lé wọn kuro li oju nyin; ẹnyin o si ní ilẹ wọn, gẹgẹ bi OLUWA Ọlọrun nyin ti sọ fun nyin.
6 Nitorina ẹ mura gidigidi lati tọju ati lati ṣe ohun gbogbo ti a kọ sinu iwé ofin Mose, ki ẹnyin ki o má ṣe yipada kuro ninu rẹ̀ si ọwọ́ ọtún tabi si ọwọ́ òsi;
7 Ki ẹnyin ki o má ṣe wá sãrin awọn orilẹ-ède wọnyi, awọn wọnyi ti o kù pẹlu nyin; ki ẹnyin má ṣe da orukọ oriṣa wọn, bẹ̃ni ki ẹ má ṣe fi wọn bura, ẹ má ṣe sìn wọn, bẹ̃ni ki ẹ má ṣe tẹriba fun wọn:
8 Ṣugbọn ki ẹnyin faramọ́ OLUWA Ọlọrun nyin, gẹgẹ bi ẹnyin ti nṣe titi di oni.
9 Nitoriti OLUWA ti lé awọn orilẹ-ède nla ati alagbara kuro niwaju nyin; ṣugbọn bi o ṣe ti nyin ni, kò sí ọkunrin kan ti o ti iduro niwaju nyin titi di oni.