Joṣ 24:11-17 YCE

11 Ẹnyin si gòke Jordani, ẹ si dé Jeriko: awọn ọkunrin Jeriko si fi ìja fun nyin, awọn Amori, ati awọn Perissi, ati awọn ara Kenaani, ati awọn Hitti, ati awọn Girgaṣi, awọn Hifi, ati awọn Jebusi; emi si fi wọn lé nyin lọwọ.

12 Emi si rán agbọ́n siwaju nyin, ti o lé wọn kuro niwaju nyin, ani awọn ọba Amori meji; ki iṣe pẹlu idà rẹ, bẹ̃ni ki iṣe pẹlu ọrun rẹ.

13 Emi si fun nyin ni ilẹ ti iwọ kò ṣe lãla si, ati ilu ti ẹnyin kò tẹ̀dó, ẹnyin si ngbé inu wọn; ninu ọgbà-àjara ati ọgbà-igi-olifi ti ẹnyin kò gbìn li ẹnyin njẹ.

14 Njẹ nitorina ẹ bẹ̀ru OLUWA, ki ẹ si ma sìn i li ododo ati li otitọ: ki ẹ si mu oriṣa wọnni kuro ti awọn baba nyin sìn ni ìha keji Odò nì, ati ni Egipti; ki ẹ si ma sìn OLUWA.

15 Bi o ba si ṣe buburu li oju nyin lati sìn OLUWA, ẹ yàn ẹniti ẹnyin o ma sìn li oni; bi oriṣa wọnni ni ti awọn baba nyin ti o wà ni ìha keji Odò ti nsìn, tabi awọn oriṣa awọn Amori, ni ilẹ ẹniti ẹnyin ngbé: ṣugbọn bi o ṣe ti emi ati ile mi ni, OLUWA li awa o ma sìn.

16 Awọn enia na dahùn, nwọn si wipe, Ki a má ri ti awa o fi kọ̀ OLUWA silẹ, lati sìn oriṣa;

17 Nitori OLUWA Ọlọrun wa, on li ẹniti o mú wa, ati awọn baba wa gòke lati ilẹ Egipti wá, kuro li oko-ẹrú, ti o si ṣe iṣẹ-iyanu nla wọnni li oju wa, ti o si pa wa mọ́ ni gbogbo ọ̀na ti awa rìn, ati lãrin gbogbo enia ti awa là kọja: