4 Emi si fun Isaaki ni Jakobu ati Esau: mo si fun Esau li òke Seiri lati ní i; Jakobu pẹlu awọn ọmọ rẹ̀ si sọkalẹ lọ si Egipti.
5 Mo si rán Mose ati Aaroni, mo si yọ Egipti lẹnu, gẹgẹ bi eyiti mo ṣe lãrin rẹ̀: lẹhin na mo si mú nyin jade.
6 Emi si mú awọn baba nyin jade kuro ni Egipti: ẹnyin si dé okun; awọn ara Egipti si lepa awọn baba nyin ti awọn ti kẹkẹ́ ati ẹlẹṣin dé Okun Pupa.
7 Nigbati nwọn kigbepè OLUWA, o fi òkunkun si agbedemeji ẹnyin ati awọn ara Egipti, o si mú okun ya lù wọn, o si bò wọn mọlẹ; oju nyin si ti ri ohun ti mo ṣe ni Egipti: ẹnyin si gbé inu aginjù li ọjọ́ pipọ̀.
8 Emi si mú nyin wá si ilẹ awọn Amori, ti ngbé ìha keji Jordani; nwọn si bá nyin jà: emi si fi wọn lé nyin lọwọ ẹnyin si ní ilẹ wọn; emi si run wọn kuro niwaju nyin.
9 Nigbana ni Balaki ọmọ Sipporu, ọba Moabu dide, o si ba Israeli jagun; o si ranṣẹ pè Balaamu ọmọ Beori lati fi nyin bú:
10 Ṣugbọn emi kò fẹ́ fetisi ti Balaamu; nitorina o nsure fun nyin ṣá: mo si gbà nyin kuro li ọwọ́ rẹ̀.