1 O si ṣe, nigbati gbogbo awọn enia rekọja Jordani tán, ni OLUWA wi fun Joṣua pe,
2 Mú ọkunrin mejila ninu awọn enia, ọkunrin kan ninu olukuluku ẹ̀ya,
3 Ki ẹnyin si paṣẹ fun wọn pe. Ẹ gbé okuta mejila lati ihin lọ lãrin Jordani, ni ibi ti ẹsẹ̀ awọn alufa gbé duro ṣinṣin nì, ki ẹnyin ki o si rù wọn kọja pẹlu nyin, ẹ si fi wọn si ibùsun, ni ibi ti ẹnyin o sùn li alẹ yi.
4 Nigbana ni Joṣua pè awọn ọkunrin mejila, ti o ti pèse silẹ ninu awọn ọmọ Israeli, ọkunrin kan ninu olukuluku ẹ̀ya:
5 Joṣua si wi fun wọn pe, Ẹ kọja lọ niwaju apoti OLUWA Ọlọrun nyin si ãrin Jordani, ki olukuluku ninu nyin ki o gbé okuta kọkan lé ejika rẹ̀, gẹgẹ bi iye ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli:
6 Ki eyi ki o le jẹ́ àmi lãrin nyin, nigbati awọn ọmọ nyin ba bère lọwọ awọn baba wọn lẹhin ọ̀la, wipe, Èredi okuta wọnyi?