11 O si ṣe, nigbati gbogbo awọn enia na rekọja tán, ni apoti OLUWA rekọja, ati awọn alufa, li oju awọn enia.
12 Awọn ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse, si rekọja ni ihamọra niwaju awọn ọmọ Israeli, gẹgẹ bi Mose ti sọ fun wọn:
13 Ìwọn ọkẹ meji enia ti o mura ogun, rekọja niwaju OLUWA fun ogun, si pẹtẹlẹ̀ Jeriko.
14 Li ọjọ́ na OLUWA gbé Joṣua ga li oju gbogbo Israeli: nwọn si bẹ̀ru rẹ̀, gẹgẹ bi nwọn ti bẹ̀ru Mose li ọjọ́ aiye rẹ̀ gbogbo.
15 OLUWA si wi fun Joṣua pe,
16 Paṣẹ fun awọn alufa ti o rù apoti ẹri nì pe, ki nwọn ki o ti inu Jordani jade.
17 Nitorina Joṣua paṣẹ fun awọn alufa wipe, Ẹ ti inu Jordani jade.