15 OLUWA si wi fun Joṣua pe,
16 Paṣẹ fun awọn alufa ti o rù apoti ẹri nì pe, ki nwọn ki o ti inu Jordani jade.
17 Nitorina Joṣua paṣẹ fun awọn alufa wipe, Ẹ ti inu Jordani jade.
18 O si ṣe, nigbati awọn alufa ti o rù apoti majẹmu OLUWA ti ãrin Jordani jade, ti awọn alufa si gbé atẹlẹsẹ̀ wọn soke si ilẹ gbigbẹ, ni omi Jordani pada si ipò rẹ̀, o si ṣàn bò gbogbo bèbe rẹ̀, gẹgẹ bi ti iṣaju.
19 Awọn enia si ti inu Jordani gòke ni ijọ́ kẹwa oṣù kini, nwọn si dó ni Gilgali, ni ìha ìla-õrùn Jeriko.
20 Ati okuta mejila wọnni ti nwọn gbé ti inu Jordani lọ, ni Joṣua tòjọ ni Gilgali.
21 O si wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Nigbati awọn ọmọ nyin yio bère lọwọ awọn baba wọn lẹhin ọ̀la wipe, Ẽredi okuta wọnyi?