20 Ati okuta mejila wọnni ti nwọn gbé ti inu Jordani lọ, ni Joṣua tòjọ ni Gilgali.
21 O si wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Nigbati awọn ọmọ nyin yio bère lọwọ awọn baba wọn lẹhin ọ̀la wipe, Ẽredi okuta wọnyi?
22 Nigbana li ẹnyin o jẹ ki awọn ọmọ nyin ki o mọ̀ pe, Israeli là Jordani yi kọja ni ilẹ gbigbẹ.
23 Nitoriti OLUWA Ọlọrun nyin mu omi Jordani gbẹ kuro niwaju nyin, titi ẹnyin fi là a kọja, gẹgẹ bi OLUWA Ọlọrun nyin ti ṣe si Okun Pupa, ti o mu gbẹ kuro niwaju wa, titi awa fi là a kọja:
24 Ki gbogbo enia aiye ki o le mọ ọwọ́ OLUWA, pe o lagbara; ki nwọn ki o le ma bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun nyin lailai.