7 Nigbana li ẹnyin o da wọn lohùn pe, Nitori a ke omi Jordani niwaju apoti majẹmu OLUWA; nigbati o rekọja Jordani, a ke omi Jordani kuro: okuta wọnyi yio si jasi iranti fun awọn ọmọ Israeli lailai.
8 Awọn ọmọ Israeli si ṣe gẹgẹ bi Joṣua ti paṣẹ, nwọn si gbé okuta mejila lati inu ãrin Jordani lọ, bi OLUWA ti wi fun Joṣua, gẹgẹ bi iye ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli; nwọn si rù wọn kọja pẹlu wọn lọ si ibùsun, nwọn si gbé wọn kalẹ nibẹ̀.
9 Joṣua si tò okuta mejila jọ lãrin Jordani, ni ibi ti ẹsẹ̀ awọn alufa ti o rù apoti majẹmu na gbé duro: nwọn si mbẹ nibẹ̀ titi di oni-oloni.
10 Nitoriti awọn alufa ti o rù apoti na duro lãrin Jordani, titi ohun gbogbo fi pari ti OLUWA palaṣẹ fun Joṣua lati sọ fun awọn enia, gẹgẹ bi gbogbo eyiti Mose palaṣẹ fun Joṣua: awọn enia na si yára nwọn si rekọja.
11 O si ṣe, nigbati gbogbo awọn enia na rekọja tán, ni apoti OLUWA rekọja, ati awọn alufa, li oju awọn enia.
12 Awọn ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse, si rekọja ni ihamọra niwaju awọn ọmọ Israeli, gẹgẹ bi Mose ti sọ fun wọn:
13 Ìwọn ọkẹ meji enia ti o mura ogun, rekọja niwaju OLUWA fun ogun, si pẹtẹlẹ̀ Jeriko.