12 Nitorina ni awọn ọmọ Israeli kò ṣe le duro niwaju awọn ọtá wọn, nwọn pẹhinda niwaju awọn ọtá wọn, nitoriti nwọn di ẹni ifibu: emi ki yio wà pẹlu nyin mọ́, bikoṣepe ẹnyin pa ohun ìyasọtọ run kuro lãrin nyin.
13 Dide, yà awọn enia na simimọ́, ki o si wipe, Ẹ yà ara nyin simimọ́ fun ọla: nitori bayi li OLUWA, Ọlọrun Israeli wipe; Ohun ìyasọtọ kan mbẹ ninu rẹ, iwọ Israeli: iwọ ki yio le duro niwaju awọn ọtá rẹ, titi ẹnyin o fi mú ohun ìyasọtọ na kuro ninu nyin.
14 Nitorina li owurọ̀ a o mú nyin wá gẹgẹ bi ẹ̀ya nyin: yio si ṣe, ẹ̀ya ti OLUWA ba mú yio wá gẹgẹ ni idile idile: ati idile ti OLUWA ba mú yio wá li agbagbole; ati agbole ti OLUWA ba mú yio wá li ọkunrin kọkan.
15 Yio si ṣe, ẹniti a ba mú pẹlu ohun ìyasọtọ na, a o fi iná sun u, on ati ohun gbogbo ti o ní: nitoriti o rú ofin OLUWA, ati nitoriti o si hù ìwakiwa ni Israeli.
16 Bẹ̃ni Joṣua dide ni kùtukutu owurọ̀, o si mú Israeli wá gẹgẹ bi ẹ̀ya wọn; a si mú ẹ̀ya Juda:
17 O si mú idile Juda wá; a si mu idile Sera: o si mú idile Sera wá li ọkunrin kọkan; a si mú Sabdi:
18 O si mú ara ile rẹ̀ li ọkunrin kọkan; a si mú Akani ọmọ Karmi, ọmọ Sabdi, ọmọ Sera ninu, ẹ̀ya Judah.