15 Joṣua ati gbogbo awọn Israeli si ṣe bi ẹniti a lé niwaju wọn, nwọn si sá gbà ọ̀na aginjú.
16 A si pe gbogbo enia ti mbẹ ni Ai jọ lati lepa wọn: nwọn si lepa Joṣua, a si fà wọn jade kuro ni ilu.
17 Kò si kù ọkunrin kan ni Ai tabi Beti-eli, ti kò jade tọ̀ Israeli: nwọn si fi ilú nla silẹ ni ṣíṣí nwọn si lepa Israeli.
18 OLUWA si wi fun Joṣua pe, Nà ọ̀kọ ti mbẹ li ọwọ́ rẹ nì si Ai; nitoriti emi o fi i lé ọ lọwọ. Joṣua si nà ọ̀kọ na ti o ni li ọwọ́ rẹ̀ si ilu na.
19 Awọn ti o ba si dide kánkan kuro ni ipò wọn, bi o si ti nàwọ́ rẹ̀, nwọn sare, nwọn si wọ̀ ilu na lọ, nwọn si gbà a; nwọn si yára tinabọ ilu na.
20 Nigbati awọn ọkunrin Ai boju wo ẹhin wọn, kiyesi i, nwọn ri ẹ̃fi ilu na ngòke lọ si ọrun, nwọn kò si lí agbara lati gbà ihin tabi ọhún sálọ: awọn enia ti o sá lọ si aginjù si yipada si awọn ti nlepa.
21 Nigbati Joṣua ati gbogbo Israeli ri bi awọn ti o ba ti gbà ilu, ti ẹ̃fi ilu na si gòke, nwọn si yipada, nwọn si pa awọn ọkunrin Ai.