17 Ṣugbọn ẹ ṣọra lọdọ enia; nitori nwọn o fi nyin le ajọ igbimọ lọwọ, nwọn o si nà nyin ninu sinagogu wọn.
18 A o si mu nyin lọ siwaju awọn bãlẹ ati awọn ọba nitori orukọ mi, fun ẹrí si wọn ati si awọn keferi.
19 Nigbati nwọn ba si fi nyin le wọn lọwọ, ẹ máṣe ṣàniyan pe, bawo tabi kili ẹnyin o wi? nitoriti a o fi ohun ti ẹnyin o wi fun nyin ni wakati kanna.
20 Nitoripe ki iṣe ẹnyin li o nsọ, ṣugbọn Ẹmí Baba nyin ni nsọ ninu nyin.
21 Arakunrin yio si fi arakunrin rẹ̀ fun pipa, ati baba yio si fi ọmọ rẹ̀ fun pipa: awọn ọmọ yio si dide si awọn obi wọn nwọn o si mu ki a pa wọn.
22 Gbogbo enia yio si korira nyin nitori orukọ mi; ṣugbọn ẹniti o ba foritì i titi fi de opin, on na ni a ó gbalà.
23 Ṣugbọn nigbati nwọn ba ṣe inunibini si nyin ni ilu yi, ẹ sá lọ si omiran: lõtọ ni mo sá wi fun nyin, ẹnyin kì ó le rekọja gbogbo ilu Israeli tan titi Ọmọ enia ó fi de.