18 Wò o, awa ngoke lọ si Jerusalemu; a o si fi Ọmọ-enia le awọn olori alufa, ati awọn akọwe lọwọ, nwọn o si da a lẹbi ikú.
19 Nwọn o si fà a le awọn keferi lọwọ lati fi i ṣe ẹlẹyà, lati nà a, ati lati kàn a mọ agbelebu: ni ijọ kẹta yio si jinde.
20 Nigbana ni iya awọn ọmọ Sebede ba awọn ọmọ rẹ̀ tọ̀ ọ wá, o bẹ̀ ẹ, o si nfẹ ohun kan li ọwọ́ rẹ̀.
21 O si bi i pe, Kini iwọ nfẹ? O wi fun u pe, Jẹ ki awọn ọmọ mi mejeji ki o mã joko, ọkan li ọwọ́ ọtún rẹ, ọkan li ọwọ́ òsi ni ijọba rẹ.
22 Ṣugbọn Jesu dahùn, o si wipe, Ẹnyin ko mọ̀ ohun ti ẹnyin mbère. Ẹnyin le mu ninu ago ti emi ó mu, ati ki a fi baptismu ti a o fi baptisi mi baptisi nyin? Nwọn wi fun u pe, Awa le ṣe e.
23 O si wi fun wọn pe, Lõtọ li ẹnyin o mu ninu ago mi, ati ninu baptismu ti a o fi baptisi mi li a o si fi baptisi nyin; ṣugbọn lati joko li ọwọ́ ọtún ati li ọwọ́ òsi mi, ki iṣe ti emi lati fi funni, bikoṣepe fun kìki awọn ẹniti a ti pèse rẹ̀ silẹ fun lati ọdọ Baba mi wá.
24 Nigbati awọn mẹwa iyokù gbọ́ ọ, nwọn binu si awọn arakunrin wọn mejeji.