3 Bi ẹnikẹni ba si wi nkan fun nyin, ẹnyin o wipe, Oluwa ni ifi wọn ṣe; lọgán ni yio si rán wọn wá.
4 Gbogbo eyi li a ṣe, ki eyi ti a ti sọ lati ẹnu wolĩ wá ki o le ṣẹ, pe,
5 Ẹ sọ fun ọmọbinrin Sioni pe, Kiyesi i, Ọba rẹ mbọ̀ wá sọdọ rẹ, o ni irẹlẹ, o joko lori kẹtẹkẹtẹ, ati lori ọmọ kẹtẹkẹtẹ.
6 Awọn ọmọ-ẹhin na si lọ, nwọn ṣe bi Jesu ti wi fun wọn.
7 Nwọn si fà kẹtẹkẹtẹ na wá, ati ọmọ rẹ̀, nwọn si tẹ́ aṣọ wọn si ẹhin wọn, nwọn si gbé Jesu kà a.
8 Ọ̀pọ ijọ enia tẹ́ aṣọ wọn si ọ̀na; ẹlomiran ṣẹ́ ẹka igi wẹ́wẹ́, nwọn si fún wọn si ọ̀na.
9 Ijọ enia ti nlọ niwaju, ati eyi ti ntọ̀ wọn lẹhin, nkigbe wipe, Hosanna fun Ọmọ Dafidi: Olubukun li ẹniti o mbọ̀ wá li orukọ Oluwa; Hosanna loke ọrun.