1 JESU si jade lọ, o ti tẹmpili kuro: awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si tọ̀ ọ wá lati fi kikọ́ tẹmpili hàn a.
2 Jesu si wi fun wọn pe, Ẹnyin kò ri gbogbo nkan wọnyi? lõtọ ni mo wi fun nyin, Kì yio si okuta kan nihinyi ti a o fi silẹ lori ekeji, ti a kì yio wó lulẹ.
3 Bi o si ti joko lori òke Olifi, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ tọ̀ ọ wá nikọ̀kọ, wipe, Sọ fun wa, nigbawo ni nkan wọnyi yio ṣẹ? kini yio si ṣe àmi wíwa rẹ, ati ti opin aiye?
4 Jesu si dahùn, o si wi fun wọn pe, Ẹ kiyesara, ki ẹnikẹni ki o máṣe tàn nyin jẹ.