22 Ménáhémù sinmi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀. Pékáhíà ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.
23 Ní ọdún kẹẹ̀dógún Ásáríyà ọba Júdà, Pékáhíà ọmọ Ménáhémù di ọba Ísírẹ́lì ní Ṣamáríà, ó sì jọba fún ọdún méjì.
24 Pékáhíà ṣe búburú lójú Olúwa. Kò yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jéróbóámù ọmọ Nébátì, èyí tí ó fa Ísírẹ́lì láti dá.
25 Ọ̀kan lára àwọn olórí ìjòyè rẹ̀ Pékà ọmọ Remalíà, dìtẹ̀ síi. Ó mú àádọ́ta àwọn ọkùnrin ti àwọn ará Gílíádì pẹ̀lú u rẹ̀. Ó pa Pékáhíà pẹ̀lú Árígóbù àti Áríè ní Kítadélì ti ààfin ọba ní Ṣamáríà. Bẹ́ẹ̀ ni Pékà pa Pékáhíà, ó sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.
26 Fún ti ìyókù iṣẹ́ ìjọba Pékáhíà, gbogbo ohun tí ó ṣe, ni a kọ sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Ísírẹ́lì
27 Ní ọdún kejìléláàdọ́ta Ásáríyà ọba Júdà, Pékà ọmọ Rèmálíà di ọba Ísírẹ́lì ní Ṣamáríà. Ó sì jọba fún ogún ọdún.
28 Ó sì ṣe búburú lójú Olúwa, kò sì yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jéróbóámù ọmọ Nébátì, èyí tí ó fa Ísírẹ́lì láti dá.