7 Ásáríyà sinmi pẹ̀lú àwọn baba a rẹ̀. A sì sin ín sí ẹ̀bá wọn ní ìlú ńlá ti Dáfídì. Jótamì ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.
8 Ní ọdún kejìdínlógójì Ásáríyà ọba Júdà. Ṣakaríà ọmọ Jéróbóámù di ọba Ísírẹ́lì ní Ṣamáríà, ó sì jọba fún oṣù mẹ́fà.
9 Ó ṣe búburú lójú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí àwọn baba rẹ̀ tí ṣe. Kò sì yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jéróbóámù ọmọ Nébátì, èyí tí ó ti fa Ísírẹ́lì láti dá.
10 Ṣálúmù ọmọ Jábésì dìtẹ̀ sí Ṣakaríà. Ó dojúkọ ọ́ níwájú àwọn ènìyàn, ó sì pa á, ó sì jọba dípò rẹ̀.
11 Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Ṣakaríà. Wọ́n kọ ọ́ sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Ísírẹ́lì.
12 Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí a sọ fún Jéhù jẹ́ ìmúṣẹ: “Àwọn ọmọ rẹ̀ yóò jókòó lórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì títí dé ìran kẹrin.”
13 Ṣálúmù ọmọ Jábésì di ọba ní ọdún kọkàndínlógójì Ùsáyà ọba Júdà, ó sì jọba ní Ṣamáríà fún oṣù kan.