8 Áhásì sì mú fàdákà àti wúrà tí a rí ní ilé Olúwa, àti nínú ìṣúrà ilé ọba, ó sì rán an sí ọba Ásíríà ní ọrẹ.
9 Ọba Ásíríà sì gbọ́ tirẹ̀: nítórí ọba Ásíríà gòkè wá sí Dámásíkù, ó sì kó o, ó sì mú un ní ìgbékùn lọ sí Kírì, ó sì pa Résínì.
10 Ọba sì lọ sí Dámásíkù láti pàdé Tigilati-Pílésérì, ọba Ásíríà, ó sì rí pẹpẹ kan tí ó wà ní Dámásíkù: Áhásì ọba sì rán àwòrán pẹpẹ náà, àti àpẹẹrẹ rẹ̀ sí Úráyà àlùfáà, gẹ́gẹ́ bí gbogbo iṣẹ́ ọ̀nà rẹ̀.
11 Úráyà àlùfáà sì kọ́ pẹpẹ náà gẹ́gẹ́ bi gbogbo èyí tí Áhásì ọba fi ránṣẹ́ síi láti Dámásíkù; bẹ́ẹ̀ ni Úráyà àlùfàá ṣe é dé ìpadàbọ̀ Áhásì ọba láti Dámásíkù.
12 Nígbà tí ọba sì ti Dámásíkù dé, ọba sì rí pẹpẹ náà: ọba sì súnmọ́ pẹpẹ náà, ó sì rúbọ lórí rẹ̀.
13 Ó sì ṣun ẹbọ ọrẹ-ṣíṣun rẹ̀ àti ọrẹ-jíjẹ rẹ̀, o si ta ohun-mímu rẹ̀ sílẹ̀, ó sì wọ́n èjẹ̀ ọrẹ-àlàáfíà rẹ̀ sí ará pẹpẹ náà.
14 Ṣùgbọ́n ó mú pẹpẹ idẹ tí ó wà níwájú Olúwa kúrò láti iwájú ilé náà, láti àárin méjì pẹpẹ náà, àti ilé Olúwa, ó sì fi í sí apá àríwá pẹpẹ náà.