18 Nígbà tí wọ́n padà dé ọ̀dọ̀ Èlíṣà, tí ó dúró ní Jẹ́ríkò, ó wí fún wọn pé, “Ṣé èmi kò sọ fún un yín kí ẹ má lọ?”
19 Àwọn ọkùnrin ìlú wí fún Èlíṣà, pé “Wò ó, Olúwa wa, ìtẹ̀dó ìlú yìí dára, gẹ́gẹ́ bí o ti rí i, ṣùgbọ́n omi náà kò dára ilẹ̀ náà sì jẹ́ aṣálẹ̀.”
20 Ó sì wí pé, “Mú àwokòtò tuntun fún mi wá, kí o sì mú iyọ̀ sí inú rẹ̀.” Wọ́n sì gbé e wá fún un.
21 Nígbà náà ó sì jáde lọ sí ibi orísun omi, ó sì da iyọ̀ sí inú rẹ̀, ó wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Èmi ti wo omi yìí sàn. Kò ní mú ikú wá mọ́ tàbí mú ilẹ̀ náà ṣá.’ ”
22 Omi náà sì ti dára ni mímu títí di òní, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí Èlíṣà ti sọ.
23 Láti ibẹ̀ Èlíṣà lọ sókè ní Bétélì gẹ́gẹ́ bí ó ti ń rìn lọ lójú ọ̀nà, àwọn ọ̀dọ́ kan jáde wá láti ìlú náà wọ́n sì fi ṣe ẹlẹ́yà. “Má a lọ sókè ìwọ apárí!” Wọ́n wí pé. “Má a lọ sókè ìwọ apárí!”
24 Ó sì yípadà, ó sì wò wọ́n ó sì fi wọ́n bú ní orúkọ Olúwa. Nígbà náà béárì méjì sì jáde wá láti inú igbó ó sì lu méjìlélógójì (42) lára àwọn ọ̀dọ́ náà.