2 Sámúẹ́lì 4:2-8 BMY

2 Ọmọ Ṣọ́ọ̀lù sì ní ọkùnrin méjì tí í ṣe olórí ẹgbẹ́ ogun: a ń pe orúkọ ọ̀kan ní Báánà, àti orúkọ ìkẹjì ní Rákábù, àwọn ọmọ Rímímónì ará Béérótì ti àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì (nítorí pé a sì ka Béérótì pẹ̀lú Bẹ́ńjámínì).

3 Àwọn ará Béérótì sì ti sá lọ sí Gítaímù, wọ́n sì ṣe àtìpó níbẹ̀ títí ó fi di ọjọ́ òní yìí.

4 (Jónátanì ọmọ Ṣọ́ọ̀lù sì ti bí ọmọkùnrin kan tí ẹsẹ̀ rẹ̀ rọ, òun sì jẹ́ ọdún márùn-ún, nígbà tí ìhìn dé ní ti Ṣọ́ọ̀lù àti Jónátanì láti Jésírẹẹlì wá, olùtọ́ rẹ̀ sì gbé e, o sì sá lọ, ó sì ṣe, bí ó sì ti ń yára láti sá lọ, òun sì ṣubú, ó sì ya arọ. Orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Méfíbóṣétì.)

5 Àwọn ọmọ Rímímónì, ará Béérótì, Rákábù àti Báánà sì lọ wọ́n sì wá sí ilé Iṣíbóṣétì ní ọsán gangan, òun sì sinmi lórí ibùsùn kan ní ọjọ́ kan-rí.

6 Sì wò ó, bí Olùsọ́ ẹnú ọ̀nà ilé náà ti ń gbọn àwọn pàǹtí, ó tòògbé ó sì sùn lọ, wọ́n sì wá sí àárin ilé náà, wọ́n sì ṣe bí ẹni pé wọ́n ń fẹ́ mú àlìkámà; (wọ́n sì gún un lábẹ́ inú: Rékábù àti Báánà arákùnrin rẹ̀ sì sá lọ).

7 Nígbà tí wọ́n wọ ilé náà lọ, òun sì dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ̀ nínú iyàrá rẹ̀, wọ́n sì pa á, wọ́n sì bẹ́ ẹ lórí, wọ́n gbé orí sá lọ, wọ́n sì fi gbogbo òru rìn ni pẹ̀tẹ́lẹ̀ náà.

8 Wọ́n sì gbé orí Íṣíbóṣétì tọ Dáfídì wá ní Hébírónì, wọ́n sì wí fún ọba pé, “Wò ó, orí Íṣíbóṣétì ọmọ Ṣọ́ọ̀lù ọ̀ta rẹ, tí ó ti ń wá ẹ̀mí rẹ kíri, Olúwa ti gbẹ̀san fún ọba Olúwa mi lónìí lára Ṣọ́ọ̀lù àti lára irú-ọmọ rẹ̀.”