2 Sámúẹ́lì 4:4-10 BMY

4 (Jónátanì ọmọ Ṣọ́ọ̀lù sì ti bí ọmọkùnrin kan tí ẹsẹ̀ rẹ̀ rọ, òun sì jẹ́ ọdún márùn-ún, nígbà tí ìhìn dé ní ti Ṣọ́ọ̀lù àti Jónátanì láti Jésírẹẹlì wá, olùtọ́ rẹ̀ sì gbé e, o sì sá lọ, ó sì ṣe, bí ó sì ti ń yára láti sá lọ, òun sì ṣubú, ó sì ya arọ. Orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Méfíbóṣétì.)

5 Àwọn ọmọ Rímímónì, ará Béérótì, Rákábù àti Báánà sì lọ wọ́n sì wá sí ilé Iṣíbóṣétì ní ọsán gangan, òun sì sinmi lórí ibùsùn kan ní ọjọ́ kan-rí.

6 Sì wò ó, bí Olùsọ́ ẹnú ọ̀nà ilé náà ti ń gbọn àwọn pàǹtí, ó tòògbé ó sì sùn lọ, wọ́n sì wá sí àárin ilé náà, wọ́n sì ṣe bí ẹni pé wọ́n ń fẹ́ mú àlìkámà; (wọ́n sì gún un lábẹ́ inú: Rékábù àti Báánà arákùnrin rẹ̀ sì sá lọ).

7 Nígbà tí wọ́n wọ ilé náà lọ, òun sì dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ̀ nínú iyàrá rẹ̀, wọ́n sì pa á, wọ́n sì bẹ́ ẹ lórí, wọ́n gbé orí sá lọ, wọ́n sì fi gbogbo òru rìn ni pẹ̀tẹ́lẹ̀ náà.

8 Wọ́n sì gbé orí Íṣíbóṣétì tọ Dáfídì wá ní Hébírónì, wọ́n sì wí fún ọba pé, “Wò ó, orí Íṣíbóṣétì ọmọ Ṣọ́ọ̀lù ọ̀ta rẹ, tí ó ti ń wá ẹ̀mí rẹ kíri, Olúwa ti gbẹ̀san fún ọba Olúwa mi lónìí lára Ṣọ́ọ̀lù àti lára irú-ọmọ rẹ̀.”

9 Dáfídì sì dá Rákábù àti Báánà arakùnrin rẹ̀, àwọn ọmọ Rímímónì ará Béérótì lóhùn, ó sì wí fún wọn pé, “Bí Olúwa ti ń bẹ, ẹni tí ó gba ẹ̀mí mi lọ́wọ́ gbogbo ìpọ́njú.

10 Nígbà tí ẹnìkan rò fún mi pé, ‘Wò ó, Ṣọ́ọ̀lù ti kú,’ lójú ara rẹ̀ òun sì jásí ẹni tí ó mú ìhìnrere wá, èmi sì mú un, mo sì pa á ní Síkílágì, ẹni tí ó ṣebí òun ó rí nǹkan gbà nítorí ìhìn rere rẹ̀.