42 Ṣùgbọ́n Olúwa sọ fún mi pé, “Sọ fún wọn, ‘Ẹ má se gòkè lọ láti jà torí pé èmi kì yóò wà pẹ̀lú u yín. Àwọn ọ̀ta a yín yóò sì sẹ́gun yín.’ ”
43 Bẹ́ẹ̀ ni mo sọ fún un yín, ẹ kò sì gbọ́, ẹ sọ̀tẹ̀ sí òfin Olúwa, pẹ̀lú ìgbéraga yín ẹ gòkè lọ sí ìlú olókè náà.
44 Àwọn ará Ámórì tí ń gbé ní àwọn òkè náà, dojú kọ yín bí àgbájọpọ̀ oyin. Wọ́n sì lù yín bolẹ̀ látí Séírì títí dé Hómà.
45 Ẹ padà, ẹ sì sunkún níwájú Olúwa, òun kò sì fetí sí igbe ẹkún yín, Ó sì kọ etí dídi sí i yín.
46 Báyìí ni ẹ sì dúró ní Kádésì fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti ṣe.