11 Níbi tí Olúwa Ọlọ́run yín yóò yàn bí ibùgbé fún orúkọ rẹ̀. Níbẹ̀ ni kí ẹ mú gbogbo ohun tí mo pàṣẹ fún un yín wá: àwọn ọrẹ ẹ yín àti àwọn ẹbọ síṣún, ìdámẹ́wàá yín àti ọrẹ àkànṣe, àti gbogbo ohun ìní yín tí ẹ ti yàn, èyí tí ẹ ti jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Olúwa.
12 Kí ẹ máa yọ̀ níwájú Olúwa Ọlọ́run yín níbẹ̀, ẹ̀yin, àwọn ọmọkùnrin yín, àwọn ọmọbìnrin yín, ìránṣẹ́-bìnrin àti ìránṣẹ́-kùnrin yín, àti àwọn Léfì láti ìlú u yín, tí wọn kò ní ìpín tàbí ogún tiwọn.
13 Ẹ sọ́ra kí ẹ má ṣe rú ẹbọ siṣun yín ní ibikíbi tí ẹ̀yin fẹ́.
14 Ibi tí Olúwa yóò yàn láàrin àwọn ẹ̀yà a yín nìkan ni kí ẹ ti máa rú ẹbọ yín, kí ẹ sì máa kíyèsí ohun gbogbo tí mo pàṣẹ fún un yín níbẹ̀.
15 Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀, ẹ lọ pa àwọn ẹran yín ní èyíkéyìí nínú àwọn ìlú u yín, kí ẹ sì jẹ ẹran náà tó bí ẹ ti fẹ́, bí ẹ ti ń ṣe sí àgbọ̀nrín àti èṣúó, gẹ́gẹ́ bí ìbùkún Olúwa Ọlọ́run yín tí ó fi fún un yín, àti ẹni mímọ́ àti aláìmọ́ ni ó lè jẹ nínú àwọn ẹran náà.
16 Ṣùgbọ́n ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ wọn, ẹ dàá sílẹ̀ bí omi.
17 Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ìdámẹ́wàá oúnjẹ yín, wáìnì tuntun, òróró, àkọ́bí àwọn màlúù yín, tàbí ti ewúrẹ́ ẹ yín, ohunkóhun tí ó jẹ́ ẹ̀jẹ́, ọrẹ àtinúwá, tàbí ẹ̀bùn pàtàkì ní ìlú ẹ̀yin tìkárayín.