8 Ẹ má ṣe ṣe bí a tí ṣe lónìí yìí, tí olúkúlùkù ń ṣe ohun tí ó wù ú.
9 Níwọ̀n ìgbà tí ẹ ti dé ibi ìsinmi, àti ibi ogún tí Olúwa Ọlọ́run yín fún un yín.
10 Ṣùgbọ́n ẹ ó la Jọ́dánì kọjá, ẹ ó sì máa gbé ní ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run yín fún un yín bí ìní, yóò sì fún un yín ní ìsinmi, kúrò láàrin àwọn ọ̀ta a yín, tí ó yí i yín ká, kí ẹ báà lè máa gbé láìléwu.
11 Níbi tí Olúwa Ọlọ́run yín yóò yàn bí ibùgbé fún orúkọ rẹ̀. Níbẹ̀ ni kí ẹ mú gbogbo ohun tí mo pàṣẹ fún un yín wá: àwọn ọrẹ ẹ yín àti àwọn ẹbọ síṣún, ìdámẹ́wàá yín àti ọrẹ àkànṣe, àti gbogbo ohun ìní yín tí ẹ ti yàn, èyí tí ẹ ti jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Olúwa.
12 Kí ẹ máa yọ̀ níwájú Olúwa Ọlọ́run yín níbẹ̀, ẹ̀yin, àwọn ọmọkùnrin yín, àwọn ọmọbìnrin yín, ìránṣẹ́-bìnrin àti ìránṣẹ́-kùnrin yín, àti àwọn Léfì láti ìlú u yín, tí wọn kò ní ìpín tàbí ogún tiwọn.
13 Ẹ sọ́ra kí ẹ má ṣe rú ẹbọ siṣun yín ní ibikíbi tí ẹ̀yin fẹ́.
14 Ibi tí Olúwa yóò yàn láàrin àwọn ẹ̀yà a yín nìkan ni kí ẹ ti máa rú ẹbọ yín, kí ẹ sì máa kíyèsí ohun gbogbo tí mo pàṣẹ fún un yín níbẹ̀.