18 òòdẹ̀, onírúurú ẹyẹ odò mìíràn, atọ́ka àti àdán.
19 Àti gbogbo kòkòrò tí ń fò tí wọ́n ń kọ́wọ̀ọ́ rín jẹ́ aláìmọ́ fun un yín, ẹ má ṣe jẹ wọ́n.
20 Ṣùgbọ́n ẹ lè jẹ èyíkéyí ẹ̀dá abìyẹ́ tí ó bá mọ́.
21 Ẹ má ṣe jẹ ohun tí ó ti kú sílẹ̀. Ẹ lè fún àwọn àjèjì tí ń gbé ní èyíkéyí nínú ìlú yín. Òun lè jẹ ẹ́ tàbí kí ẹ tà á fún àwọn àjèjì. Ṣùgbọ́n ènìyàn mímọ́ fún Olúwa Ọlọ́run yín ni ẹ̀yin jẹ́.Má ṣe ṣe ewúrẹ́ nínú wàrà ìyá rẹ̀.
22 Ẹ rí i dájú pé ẹ̀ ń fi ìdá kan nínú mẹ́wàá nínú irè oko yín lọ́dọọdún pamọ́ sí apákan
23 Ẹ jẹ ìdámẹ́wàá, oúnjẹ yín, wáìnì tuntun, òróró, àti àkọ́bí àwọn màlúù yín àti ewúrẹ́ ẹ yín, níwájú Olúwa Ọlọ́run yín, ní ibi tí yóò yàn bí ibùgbé orúkọ rẹ̀. Kí ẹ lè kọ́ bí a ṣé ń bọlá fún Olúwa Ọlọ́run yín nígbà gbogbo.
24 Bí ibẹ̀ bá jìn tí Olúwa Ọlọ́run rẹ sì ti bùkún fún ọ, tí o kò sì le ru àwọn ìdámẹ́wàá rẹ (nítorí pé ibi tí Olúwa yóò yàn láti fi orúkọ rẹ̀ sí jìnnà jù).