23 Ẹ jẹ ìdámẹ́wàá, oúnjẹ yín, wáìnì tuntun, òróró, àti àkọ́bí àwọn màlúù yín àti ewúrẹ́ ẹ yín, níwájú Olúwa Ọlọ́run yín, ní ibi tí yóò yàn bí ibùgbé orúkọ rẹ̀. Kí ẹ lè kọ́ bí a ṣé ń bọlá fún Olúwa Ọlọ́run yín nígbà gbogbo.
24 Bí ibẹ̀ bá jìn tí Olúwa Ọlọ́run rẹ sì ti bùkún fún ọ, tí o kò sì le ru àwọn ìdámẹ́wàá rẹ (nítorí pé ibi tí Olúwa yóò yàn láti fi orúkọ rẹ̀ sí jìnnà jù).
25 Ẹ pààrọ̀ àwọn ìdámẹ́wàá yín sówó, ẹ mú owó náà lọ sí ibi tí Olúwa yóò yàn.
26 Fi owó náà ra ohunkóhun tí o bá fẹ́, màlúù, àgùntàn, wáìnì, tàbí ọtí líle, tàbí ohunkóhun tí o bá fẹ́. Kí ìwọ àti ìdílé rẹ sì jẹ ẹ́ níwájú Olúwa níbẹ̀ kí ẹ sì máa yọ̀.
27 Ẹ má ṣe gbàgbé àwọn Léfì tí ó ń gbé nì ilú yín, nítorí pé wọn kò ní ìpín kan tàbí ogún kan tí í se tiwọn.
28 Ní òpin ọdún mẹ́tamẹ́ta, ẹ mú gbogbo ìdámẹ́wàá irè oko àwọn ọdún náà, kí ẹ kó wọn jọ ní ìlú yín.
29 Kí àwọn Léfì (tí kò ní ìpín tàbí ogún ti wọn) àti àwọn àlejò, àwọn aláìní baba, àti àwọn opó tí ń gbé ìlú yín lè wá, kí wọn sì jẹ kí wọn sì yó, kí Olúwa Ọlọ́run rẹ leè bùkún fún ọ, nínú gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.