6 Ẹ lè jẹ gbogbo ẹranko tí pátakò ẹṣẹ̀ rẹ̀ kì í se méjì tí ó sì tún jẹ àpọ̀jẹ.
7 Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀ nínú gbogbo ẹran tí ń jẹ àpọ̀jẹ tí ó sì tún ya pátakò ẹṣẹ̀ tí ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ni: ràkunmí, ehoro, àti ẹranko tí ó dàbí ehoro tí ń gbé inú àpáta. Bí ó tílẹ̀ jẹ́ pé wọ́n jẹ àpọ̀jẹ, ṣùgbọ́n wọn kò la pátakò, ẹṣẹ̀ a kà wọ́n sí àìmọ́ fún un yín.
8 Ẹlẹ́dẹ̀ jẹ́ àìmọ́; bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ya pátakò ẹṣẹ̀, kì í jẹ àpọ̀jẹ, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹran rẹ̀, ẹ kò sì gbọdọ̀ fọwọ́ kan òkú rẹ̀.
9 Nínú gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ń gbé inú omi, ẹ lè jẹ èyíkéyí tí ó ní lẹbẹ àti ìpẹ́.
10 Ṣùgbọ́n èyíkéyí tí kò bá ní lẹbẹ àti ìpẹ́, ẹ má ṣe jẹ ẹ́, nítorí pé àìmọ́ ni wọ́n jẹ́ fún un yín.
11 Ẹ lè jẹ ẹyẹ tí ó bá mọ́.
12 Ṣùgbọ́n ìwọ̀nyí ní ẹ kò gbọdọ̀ jẹ: idì, igún, àkàlà,