10 Nígbà náà ni kí ẹ se àjọ̀dún ọ̀ṣẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run yín, nípa pípèṣè ọrẹ àtinúwá, gẹ́gẹ́ bí ìbùkún tí Olúwa Ọlọ́run yín fún un yín.
11 Kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú Olúwa Ọlọ́run yín ní ibi tí yóò yàn ní ibùgbé fún orúkọ rẹ̀: ẹ̀yin, àwọn ọmọ yín ọkùnrin àti obìnrin, àwọn ẹrú u yín ọkùnrin àti obìnrin, àwọn Léfì tí ó wà ní ìlú u yín, àti àwọn àlejò, àwọn aláìní baba, àti àwọn opó tí ń gbé àárin yín.
12 Ẹ rántí pé ẹ ti jẹ́ ẹrú ní Éjíbítì rí, nítorí náà ẹ tẹ̀lé àwọn ìlànà wọ̀nyí dáradára.
13 Ẹ ṣe ayẹyẹ àgọ́ ìpàdé fún ọjọ́ méje lẹ́yìn ìgbà tí ẹ bá ti kórè oko yín tí ẹ ti pakà tí ẹ sì ti fún ọtí tán.
14 Ẹ máa yọ̀ ní àkókò àjọ̀dún un yín, ẹ̀yin, àwọn ọmọ yín ọkùnrin àti obìnrin, àwọn ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin yín, àti àwọn Léfì, àwọn àjòjì, àwọn aláìní baba àti àwọn opó tí ń gbé ní àwọn ìlú u yín.
15 Ọjọ́ méje ni kí ẹ fi se ayẹyẹ fún Olúwa Ọlọ́run yín ní ibi tí Olúwa yóò yàn. Nítorí pé Olúwa Ọlọ́run yín yóò bùkún un yín ní gbogbo ìkórè e yín, àti ní gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ ọ yín, ayọ̀ ọ yín yóò sì kún.
16 Ní ìgbà mẹ́ta lọ́dún ni gbogbo àwọn ènìyàn an yín gbọdọ̀ farahàn níwájú Olúwa Ọlọ́run yín ní ibi tí yóò yàn. Níbi àpèjẹ àkàrà àìwú, níbi àjọ ọ̀ṣẹ̀, àti àjọ àgọ́ ìpàdé. Kò sí ẹni tí ó gbọdọ̀ wá ṣíwájú Olúwa lọ́wọ́ òfo.