9 Nígbà tí o bá wọ ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò fi fún ọ, ìwọ kò gbọdọ̀ kọ́ láti tẹ̀lé àwọn ọ̀nà ìríra àwọn orílẹ̀ èdè náà tí ó wà níbẹ̀.
10 Má se jẹ́ kí a rí ẹnikẹ́ni láàrin yín tí ó fi ọmọ rẹ̀ ọkùnrin tàbí ọmọ rẹ̀ obìnrin la iná já (fi ọmọ rẹ rúbọ) kí ẹnikẹ́ni má ṣe lọ ṣe àyẹ̀wò, tàbí ṣẹ́ oṣó, tàbí túmọ̀ àwọn àmì nǹkan tí ń bọ̀, tàbí àjẹ́,
11 tàbí afògèdè, tàbí jẹ́ a bá iwín gbìmọ̀ tàbí oṣó tàbí abókúsọ̀rọ̀.
12 Ẹnikẹ́ni tó bá ṣe nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ìríra sí Olúwa, àti nítorí àwọn ìwà ìríra wọ̀nyí ni Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò fi lé àwọn orílẹ̀ èdè wọ̀nyí jáde kúrò níwájú rẹ.
13 O ní láti jẹ́ aláìlẹ́gàn níwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ.
14 Àwọn orílẹ̀ èdè tí ìwọ yóò gba ilẹ̀ tí wọ́n ń gbé, wọ́n fetí sí tí àwọn tí ó ń ṣe oṣó tàbí ṣe àyẹ̀wò. Ṣùgbọ́n, ní ti ìwọ, Olúwa Ọlọ́run rẹ kò fi àyè gbà ọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀.
15 Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò gbé wòlíì kan dìde gẹ́gẹ́ bí èmi láàrin àwọn arákùnrin rẹ. Tìrẹ ni kí o gbọ́.