16 Ṣùgbọ́n, nínú àwọn ìlú ti àwọn orílẹ̀ èdè tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń fún ọ gẹ́gẹ́ bí ogún, má ṣe dá ohun ẹlẹ́mìí kankan sí.
17 Pa wọ́n run pátapáta, àwọn ọmọ Hítì, ọmọ Ámórì, ọmọ Kénánì, ọmọ Pérísì, ọmọ Hífì, ọmọ Jébúsì gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti pa á láṣẹ fún ọ.
18 Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, wọn yóò kọ́ ọ láti tẹ̀lé gbogbo ohun ìríra tí wọ́n ń ṣe nínú sísin àwọn ọlọ́run wọn, ìwọ yóò sì sẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ.
19 Nígbà tí o bá dóti ìlú kan láti ọjọ́ pípẹ́, ẹ bá wọn jà láti gbà á, má ṣe pa àwọn igi ibẹ̀ run nípa gbígbé àáké lé wọn, nítorí o lè jẹ èso wọn. Má se gé wọn lulẹ̀. Nítorí igi ìgbẹ́ ha á ṣe ènìyàn bí, tí ìwọ ó máa dọ̀tí rẹ̀.
20 Ṣùgbọ́n o lè gé àwọn igi tí o mọ̀ pé wọn kì í ṣe igi eléṣo lulẹ̀ kí o sì lò wọ́n láti kọ́ ìṣọ́ sí ìlú tí ó ń bá ọ jagun, títí tí yóò fi ṣubú.