Deutarónómì 22:21-27 BMY

21 wọn yóò mú wá sí ẹnu ọ̀nà ilé baba rẹ̀ níbẹ̀ sì ni àwọn ọkùnrin ìlú rẹ̀ yóò ti sọ ọ́ ní òkúta pa. Ó ti ṣe ohun ìtìjú ní Isírẹ́lì nípa ṣíṣe aṣẹ́wó nígbà tí ó wà nílé baba rẹ̀. Ẹ ní láti pọ ohun búburú kúrò láàrin yín.

22 Bí o bá rí ọkùnrin kan tí ó bá ìyàwó ọkùnrin mìíràn lòpọ̀, àwọn méjèèjì ní láti kú. Ẹ ní láti pọ ohun búburú kúrò láàrin Ísírẹ́lì.

23 Bí ó bá ṣẹlẹ̀ wí pé ọkùnrin kan pàde wúndíá tí a ti fi fún ni láti fẹ́ láàrin ìlú tí ó sì lòpọ̀ pẹ̀lú u rẹ̀,

24 ìwọ yóò mú àwọn méjèèjì lọ sí ẹnu ibodè ìlú náà kí o sì sọ wọ́n ní ókúta pa nítorí ọmọbìnrin náà wà ní ìlú kò sì kígbe fún ìrànlọ́wọ́, àti ọkùnrin náà nítorí ó ba ìyàwó ọkùnrin mìíràn jẹ́. O ní láti wẹ búburú kúrò láàrin rẹ.

25 Ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe ìgbẹ́ ní ó ti ṣẹlẹ̀ pé ọkùnrín kan ti pàde ọmọbìnrin tí a ti fẹ́ sọ́nà tí o sì fi tagbára tagbára bá a se, ọkùnrin náà nìkan tí ó se èyí ni yóò kú.

26 Má se fi ohunkóhun ṣe ọmọbìnrin náà; kò ṣẹ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó tọ́ sí ikú. Ẹjọ́ yìí rí bí i ti ẹnìkan tí a gbámú tí ó pa aládùúgbò rẹ̀.

27 Nítorí ọkùnrin náà rí ọmọbìnrin náà ní ìta ibodè, bí ó tílẹ̀ jẹ́ pé ọmọbìnrin àfẹ́sọ́nà kígbe, kò sí ẹnìkankan níbẹ̀ láti gbà á kalẹ̀.