6 Ọmọkùnrin tí ó bá kọ́ bí ni yóò máa jẹ́ orúkọ arákùnrin rẹ̀ tí ó kú náà, kí orúkọ rẹ̀ má baá parẹ́ ní Ísírẹ́lì.
7 Ṣùgbọ́n bí ọkùnrin náà kò bá fẹ́ fi aya arákùnrin rẹ̀ ṣe aya rẹ̀, obìnrin náà yóò lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn àgbààgbà ní ẹnu bodè ìlú láti sọ pé, “Arákùnrin ọkọ ọ̀ mi kọ̀ láti gbé orúkọ arákùnrin rẹ̀ ró ní Ísírẹ́lì. Kò ní ṣe ojúṣe rẹ̀ bí arákùnrin ọkọ mi sí mi.”
8 Nígbà náà ni àwọn àgbààgbà ìlú rẹ̀ yóò pè é, wọn yóò sì bá sọ̀rọ̀. Bí ó bá sì kọ̀ jálẹ̀ tí ó bá sọ pé, “Èmi kò fẹ́ láti fẹ́ ẹ,”
9 opó arákùnrin rẹ̀ yìí yóò lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ ní ojú àwọn àgbààgbà ìlú rẹ̀, yóò yọ bàtà ẹṣẹ̀ rẹ̀ kan, yóò sì tu itọ́ sí ọkùnrin náà lójú, yóò sì wí pé, “Èyí ni ohun tí a ṣe sí ọkùnrin tí kò jẹ́ kí ìdílé arákùnrin rẹ̀ wà títí ayé.”
10 A ó sì mọ ìdílé arákùnrin yìí ní Isírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí “Ìdílé tí a yọ bàtà rẹ̀.”
11 Bí ọkùnrin méjì bá ń jà, tí ìyàwó ọ̀kan nínú wọn bá sì wá láti gbéjà ọkọ rẹ̀ kúró lọ́wọ́ ọkùnrin tí ń lù ú, tí ó sì nawọ́ di nǹkan ọkùnrin abẹ́ ẹ rẹ̀ mú.
12 Ìwọ yóò gé ọwọ́ rẹ̀ náà kúrò. Má ṣe sàánú fún un.