10 Gbọ́ràn sí Olúwa Ọlọ́run rẹ kí o sì tẹ̀lé àṣẹ àti òfin rẹ̀ tí mo ń fi fún ọ lónìí.”
11 Ní ọjọ́ kan náà Móṣè pàṣẹ fún àwọn ènìyàn pé.
12 Nígbà tí o bá ti kọjá a Jọ́dánì, àwọn ẹ̀yà yìí yóò dúró lórí òkè Gérísímù láti ṣúre fún àwọn ènìyàn: Símónì, Léfì, Júdà, Ísákárì, Jóṣẹ́fù àti Bẹ́ńjámínì.
13 Àwọn ẹ̀yà yìí yóò dúró lórí òkè Ébálì láti gé ègún: Rúbẹ́nì, Gádì, àti Ásérì, àti Ṣébúlúnì, Dánì, àti Náfitanì.
14 Àwọn ẹ̀yà Léfì yóò ké sí gbogbo ènìyàn Ísírẹ́lì ní ohùn òkè:
15 “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó fín ère tàbí gbẹ́ òrìṣà ohun tí ó jẹ́ ìríra níwájú Olúwa, iṣẹ́ ọwọ́ onísọ̀nà tí ó gbé kalẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀.”Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
16 “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó dójú ti baba tàbí ìyá rẹ̀”Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”