2 Gbogbo ìbùkún yìí yóò wá sóríì rẹ yóò sì máa bá ọ lọ bí o bá gbọ́ràn sí Olúwa Ọlọ́run rẹ:
3 Ìbùkún ni fún ọ ni ìlú, ìbùkún ni fún ọ ní oko.
4 Ìbùkún ni fún ọmọ inú ù rẹ, àti èṣo ilẹ̀ rẹ, àti irú ohun ọ̀sìn rẹ àti ìbísí i màlúù rẹ àti ọmọ àgùntàn rẹ.
5 Ìbùkún ni fún agbọ̀n rẹ àti fún ọpọ́n ìpo ìyẹ̀fun rẹ.
6 Ìbùkún ni fún ọ nígbà tí Ìwọ bá wọlé, ìbùkún ni fún ọ nígbà tí ìwọ bá jáde.
7 Olúwa yóò gbà fún ọ pé gbogbo ọ̀ta tí ó dìde sí ọ yóò bì subú níwájú rẹ. Wọn yóò tọ̀ ọ́ wá ní ọ̀nà kan ṣùgbọ́n wọn yóò sá fún ọ ní ọ̀nà méje.
8 Olúwa yóò rán ìbùkún sí ọ àti sí ohun gbogbo tí o bá dáwọ́ ọ rẹ lé. Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò bùkún un fún ọ nínú ilẹ̀ tí ó ń fi fún ọ.