38 Ìwọ yóò gbin irúgbìn púpọ̀ ṣùgbọ́n ìwọ yóò kórè kékeré, nítorí eṣú yóò jẹ̀ ẹ́ run.
39 Ìwọ yóò gbin ọgbà àjàrà púpọ́ ìwọ yóò sì ro wọ́n ṣùgbọ́n kò ní mú wáìnì náà tàbí kó àwọn èṣo jọ, nítorí kòkòrò yóò jẹ wọ́n run.
40 Ìwọ yóò ní igi ólífì jákèjádò ilẹ̀ rẹ ṣùgbọ́n ìwọ kò ní lo òróró náà, nítorí ólífì náà yóò rẹ̀ dànù.
41 Ìwọ yóò ní àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin ṣùgbọ́n ìwọ kò ní pa wọ́n mọ́, nítorí wọn yóò lọ sí ìgbèkùn.
42 Ọ̀wọ́ eṣú yóò gba gbogbo àwọn igi rẹ àti àwọn èso ilẹ̀ rẹ.
43 Àlejò tí ń gbé láàrin rẹ yóò gbé sókè gíga jù ọ́ lọ, ṣùgbọ́n ìwọ yóò máa di ìrẹ̀sílẹ̀.
44 Yóò yà ọ́, ṣùgbọ́n o kì yóò yà á, òun ni yóò jẹ́ orí, ìwọ yóò jẹ́ ìrù.