12 Nínú àwọn ilẹ̀ tí a gbà ní ìgbà náà, mo fún àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti àwọn ọmọ Gádì, ní ilẹ̀ tí ó wà ní àríwá Áréórì níbi odò Ánónì, pọ̀ mọ́ ìdajì ilẹ̀ òkè Gílíádì pẹ̀lú gbogbo ìlú wọn.
13 Gbogbo ìyókù Gílíádì àti gbogbo Básánì, ní ilẹ̀ ọba Ógù ni mo fún ìdajì ẹ̀yà Mánásè. (Gbogbo agbégbé Ágóbù ni Básánì tí a mọ̀ sí ilẹ̀ àwọn ará Ráfátì.
14 Jáérì ọ̀kan nínú àwọn ìran Mánásè gba gbogbo agbégbé Ágóbù títí dé ààlà àwọn ará Gésúrì àti àwọn ará Mákátì; a sọ ibẹ̀ ní orúkọ rẹ̀ torí èyí ni Básánì fi ń jẹ́ Hafoti-Jáírì títí di òní.)
15 Mo sì fi Gílíádì fún Mákírì,
16 ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti Gádì ni mo fún ní ilẹ̀ láti Gílíádì lọ dé odò Ánónì (àárin odò náà sì jẹ́ ààlà) títí ó fi dé odò Jábókù. Èyí tí i ṣe ààlà àwọn ará Ámónì.
17 Apá ìwọ̀ óòrùn rẹ̀ ni Jọ́dánì, ní aginjù, láti Kínérétì títí dé òkun aginjù (Tí í ṣe òkun iyọ̀) ní ihà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Písígà.
18 Mo pàṣẹ fún un yín ní ìgbà náà pé, “Olúwa Ọlọ́run yín ti fi ilẹ̀ yìí fún un yín láti ni ín. Ṣùgbọ́n, gbogbo àwọn ọkùnrin yín tí ó lera tí wọ́n sì ti dira ogun, gbọdọ̀ kọjá ṣíwájú àwọn arákùnrin yín: ará Ísírẹ́lì.