26 Ṣùgbọ́n torí i ti yín, Olúwa Ọlọ́run bínú sí mi kò sì gbọ́ tèmi. Olúwa sọ wí pé, “Ó tó gẹ́ẹ́, ìwọ kò gbọdọ̀ sọ ohunkóhun lórí ọ̀rọ̀ yìí sí mi mọ́.
27 Gòkè lọ sí orí òkè Písígà, sì wò yíká ìwọ̀ oòrùn, ìlà oòrun, àríwá àti gúúsù. Fi ojú ara rẹ wo ilẹ̀ náà níwọ̀n bí ìwọ kò tí ní kọjá Jọ́dánì yìí.
28 Ṣùgbọ́n yan Jósúà, kí o sì gbà á níyànjú, mú un lọ́kàn le, torí pé òun ni yóò ṣíwájú àwọn ènìyàn wọ̀nyí kọjá, yóò sì jẹ́ kí wọn jogún ilẹ̀ náà tí ìwọ yóò rí.”
29 Báyi ni a dúró ní àfonífojì ní ẹ̀bá Bétí-Péórì.