1 Nígbà náà ni Móṣè jáde tí ó sì sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí gbogbo Ísírẹ́lì pé:
2 “Mo jẹ́ ọmọ ọgọ́fà ọdún báyìí àti pé èmi kò ni lè darí i yín mọ́. Olúwa ti sọ fún mi pé, ‘O kò ní kọjá Jọ́dánì.’
3 Olúwa Ọlọ́run rẹ fúnra rẹ̀ ni yóò rékọjá fún ọ. Yóò pa àwọn orílẹ̀ èdè yìí run níwájú ù rẹ, ìwọ yóò sì mú ìní ilẹ̀ wọn, Jósúà náà yóò rékọjá fún ọ, bí Olúwa ti sọ.
4 Olúwa yóò sì ṣe fún wọn ohun tí ó ti ṣe sí Ṣíhónì àti sí Ógù ọba Ámórì, tí ó parun pẹ̀lú ilẹ̀ ẹ wọn.
5 Olúwa yóò fi wọ́n fún ọ, kí o sì ṣe sí wọn gbogbo èyí tí mo ti pa láṣẹ fún ọ.
6 Jẹ́ alágbára kí o sì ní ìgboyà. Má se bẹ̀rù tàbí jáyà nítorí i wọn, nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń lọ pẹ̀lú ù rẹ; Òun kò ní fi ọ́ sílẹ̀ tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀.”
7 Nígbà náà ni Mósè pe Jóṣúà ó sì wí fún un níwájú gbogbo Ísírẹ́lì pé, “Jẹ́ alágbára àti onígboyà, nítorí o ní láti lọ pẹ̀lú àwọn ènìyàn wọ̀nyí sí ilẹ̀ tí Olúwa búra fún àwọn baba ńlá a wọn láti fún wọn, kí o sì pín ilẹ̀ náà láàrin wọn bí ogún wọn.