22 Nígbà náà ni Móṣè kọ orin yìí kalẹ̀ ní ọjọ́ náà ó sì kọ ọ́ sí Ísírẹ́lì.
23 Olúwa sì fún Jósúà ọmọ Núnì ní àṣẹ yìí: “Jẹ́ alágbára àti onígboyà, nítorí ìwọ yóò mú Ísírẹ́lì wá sí ilẹ̀ tí mo ṣèlérí fún wọn lórí ìbúra, èmi fúnra à mi yóò sì wà pẹ̀lú ù rẹ.”
24 Lẹ́yìn ìgbà tí Móṣè ti parí i kíkọ ọ̀rọ̀ òfin yìí sínú ìwé láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin,
25 ó sì fi àṣẹ yìí fún àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n ń gbé àpótí i májẹ̀mú Olúwa:
26 “Gba ìwé òfin yìí kí o sì fi sí ẹ̀gbẹ́ àpótí i májẹ̀mú Olúwa Ọlọ́run rẹ. Níbẹ̀ ni yóò wà bí ẹ̀rí sí ọ.
27 Nítorí mo mọ irú ọlọ̀tẹ̀ àti ọlọ́rùn líle tí ẹ jẹ́. Bí o bá ṣe ọlọ̀tẹ̀ sí Olúwa nígbà tí mo pàpà wà láyé Pẹ̀lú u yín, báwo ní ẹ ó ti ṣe ọlọ̀tẹ̀ tó nígbà tí mo bá kú tan!
28 Ẹ péjọ pọ̀ ṣíwájú ù mi gbogbo àgbà ẹ̀yà yín àti àwọn aláṣẹ yín, kí èmi lè sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí etíìgbọ́ ọ́ wọn.