5 Olúwa yóò fi wọ́n fún ọ, kí o sì ṣe sí wọn gbogbo èyí tí mo ti pa láṣẹ fún ọ.
6 Jẹ́ alágbára kí o sì ní ìgboyà. Má se bẹ̀rù tàbí jáyà nítorí i wọn, nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń lọ pẹ̀lú ù rẹ; Òun kò ní fi ọ́ sílẹ̀ tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀.”
7 Nígbà náà ni Mósè pe Jóṣúà ó sì wí fún un níwájú gbogbo Ísírẹ́lì pé, “Jẹ́ alágbára àti onígboyà, nítorí o ní láti lọ pẹ̀lú àwọn ènìyàn wọ̀nyí sí ilẹ̀ tí Olúwa búra fún àwọn baba ńlá a wọn láti fún wọn, kí o sì pín ilẹ̀ náà láàrin wọn bí ogún wọn.
8 Olúwa fúnra rẹ̀ ń lọ níwájú rẹ yóò sì wà pẹ̀lú ù rẹ; kò ní fi ọ́ sìlẹ̀ tàbí kọ̀ ọ́ sìlẹ̀. Má ṣe bẹ̀rù má sì ṣe fòyà.”
9 Nígbà náà ni Móṣè kọ òfin yìí kalẹ̀ ó sì fi fún àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì, tí ń gbé àpótí i májẹ̀mú Olúwa, àti fún gbogbo àwọn àgbà ní Ísírẹ́lì.
10 Nígbà náà ni Móṣè pàṣẹ fún wọn, “Ní òpin ọdún méje méje, ní àkókò ọdún ìdásílẹ̀, nígbà àjọ àwọn àgọ́.
11 Nígbà tí gbogbo Ísírẹ́lì bá wá láti fi ara hàn níwájú Olúwa Ọlọ́run wa ní ibi tí yóò yàn, ìwọ yóò ka òfin yìí níwájú wọn sí etí ìgbọ́ wọn.