17 Wọ́n rúbọ sí iwin búburú, tí kì í ṣe Ọlọ́run,ọlọ́run tí wọn kò mọ̀ rí,ọlọ́run tí ó sẹ̀sẹ̀ farahàn láìpẹ́,ọlọ́run tí àwọn baba yín kò bẹ̀rù.
18 Ìwọ kò rántí Àpáta, tí ó bí ọ;o sì gbàgbé Ọlọ́run tí ó dá ọ.
19 Olúwa sì rí èyí ó sì kọ̀ wọ́n,nítorí tí ó ti bínú nítori ìwà ìmúnibínú àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin ìn rẹ.
20 Ó sì wí pé, “Èmi yóò pa ojú ù mi mọ́ kúrò lára wọn,èmi yóò sì wò ó bí ìgbẹ̀yìn in wọn yóò ti rí;nítorí wọ́n jẹ́ ìran alágídí,àwọn ọmọ tí kò sí ìgbàgbọ́ nínú un wọn.
21 Wọ́n fi mí jowú nípa ohun tí kì í ṣe Ọlọ́run,wọ́n sì fi ohun aṣán an wọn mú mi bínú.Èmi yóò mú wọn kún fún ìlara láti ọ̀dọ̀ àwọn tí kì í ṣe ènìyàn;èmi yóò sì mú wọn bínú láti ọ̀dọ̀ aṣiwèrè orílẹ̀ èdè.
22 Nítorí pé iná kan ràn nínú ìbínú un mi,yóò sì jó dé ipò ikú ní ìṣàlẹ̀.Yóò sì run ayé àti ìkórè e rẹ̀yóò sì tiná bọ ìpìlẹ̀ àwọn òkè ńlá.
23 “Èmi yóò kó àwọn ohun búburú lé wọn lóríèmi ó sì na ọfà mi tán sí wọn lára.